Niwaju igbimo to n gbo esun to
jeyo latari ibo to re koja ni Atiku gbe oro e lo bayii, okunrin naa ti ni ki
won gba oun lowo awon omo egbe oselu APC ati Aare Muhammed Buhari, nitori nise
ni won fowo ola gba oun loju, ti won si yi ibo aare mo oun lowo.
Okunrin oloselu omo ipinle
Adamawa yii so pe, gbogbo ohun to ba gba pata loun yoo fun un labe ofin lati fi
le Buhari kuro nile ijoba, nitori oun lawon omo Nigeria dibo won fun, nitori
ijoba Buhari ti su won, ati pe eru nla ni won fi yi i mo oun lowo.
Sa o, agbenuso fun egbe oselu
APC, Mallam Issa Onilu ti so pe iranran lasan ni Atiku n se, nitori pe oun ko lo
wole ibo aare to n pariwo e kiri wi pe won yi mo oun lowo yii.
O fi kun un pe ibo milionu kan
ati egberun lona egbeta ti Atiku so pe oun fi na Buhari yii, nibo gan-an lo ti
ri i. O ni ko ma je pe awon babalawo ti won n gbowo lowo Atiku ni won riran
ohun si i wi pe oun lo maa wole, ati pe boya igbagbo e ninu ohun tawon yen so
gan an lo mu un maa da ara e laamu kiri.
Issa Onilu fi kun un pe alawada
lasan ni Atiku ati egbe oselu PDP e, nitori APC ati Buhari ti goke odo bayii,
bee awon omo Nigeria ti dibo fun won, awon lawon yoo si sejoba, ki okunrin naa
tete taji ninu iranran to n se.
0 Comments