GBAJUMO

ATIKU YARI O! AWON AGBEJORO NLA NLA LO N KO JO LATI BA BUHARI WO O NILE-EJO

Lati mu ileri e se lori bo se so pe oun ko ni i gba ki egbe oselu APC ati Aare Muhammed Buhari fi eru yan oun je ninu ibo Aare to koja, Alhaji Atiku Abubakar ti ko awon amofin agba ti won gboju-gbonu niwaju adajo jo, o si ti so pe o di dandan ki idajo ododo waye lori ibo Aare to koja.
Oga nla kan nidii ise amofin, Dokita Livy Uzoukwu ni okunrin omo ipinle Adamawa yii gba, ti yoo saaju awon amofin yooku ti won fe ba Atiku rojo niwaju adajo.
Wesde ojo ketadinlogbon osu yii ni ajo INEC kede wi pe Aare Muhammed Buhari lo jawe olubori ninu eto idibo to waye lojo ketalelogun osu yii, iyen ojo Abameta Satide to koja. Ni kete ti won ti kede wi pe Buhari lo wole bayii ni Atiku Abubakar, eni ti se oludije loruko egbe oselu PDP ti so pe oun ko gba esi ibo naa, nitori pe eru patapata ni won lo foun ninu idibo ohun.
Ninu oro e lo ti so pe, “Ni bayii, mo ti se ifiliole awon agbejoro ti won yoo gba ejo wa ro niwaju adajo lati fi gba ipo wa pada lowo awon APC, nitori eru ponlebe ni won se pelu ifowosowopo ajo INEC.


Siwaju si i, ninu iwe apileko ti  awon iko oludije fun ipo Aare, Alhaji Atiku Abubakar fowo si naa ni won ti so pe, nise ni ijoba apapo labe isakoso Muhammed Buhari n dun ikoko mo awon amofin agba meji kan, Kanu Agabi ati Ipkeazu lori bi won se fe kopa ninu ejo ti Atiku fe pe Aare Muhammed Buhari, ajo INEC, egbe oselu APC atawon mi-in toro ohuin kan gbongbon.

Post a Comment

0 Comments