Satide ogbonjo osu yii ni ayeye
Maould Nabbiyy ijo AZAWIYATU HUBU ROSUL HAMMOWIYAT TIJANIYAT yoo waye niluu
Ode-Remo nipinle Ogun.
Ninu atejade ti alakooso ijo
nla yii, Sheik Haruna Olorungbebe fowo si lo ti fidi e mule wi pe, ayeye ojoobi
Anobi yii ni yoo je eleekefa ti ijo ohun yoo se ninu ilu naa.
Baba Remo gege bi awon eeyan
tun se maa n pe Sheik Haruna Olorungbebe fi kun un pe, “Akanse nla ni Maolud todun
yii maa je nitori a fe ki awon eeyan wa janfaani nla, idanilekoo yoo wa, bee
lawon eto olokan-o-jokan nilana esin Islam la o se lojo naa, ninu eyi tawon eeyan
yoo ti janfaani repete, ti won yoo si mu alubarika lo sile.”
Oniwaasi ojo naa ni Fadeelat Sheik
Alh. Abdul-Wahab Saa-Dallah Oniponmo, aago mesan-an asale ni won so pe eto ohun
yoo bere ni Agbero Motor Garage, Old Lagos/Ibadan expressway, Ode-Remo, nipinle
Ogun.
Awon olorin Islam ti yoo forin
emi bo awon eeyan lojo naa ni Alhaji Muh. Kazeem Onaola ati Ustaz Kamaldeen Mopelola
Idowu, eni tawon eeyan tun mo si Kiniun Anobi.
0 Comments