GBAJUMO

JIMI AGBAJE TI KI SANWO-OLU KU ORIIRE *SUGBON NISE LAWON OMO EGBE PDP KAN N BINU O


Bo tile je pe Ogbeni Jimi Agbaje, oludije fun ipo gomina labe asia egbe oselu PDP to fidi remi l’Ekoo ti ki Babajide Sanwo-Olu ku oriire, sibe awon omo egbe naa n binu o, won ni oun gan an lo fa a ijakule egbe naa lawon ibi kan l’Ekoo.
Okan ninu awon omo egbe oselu naa to ba wa soro salaye pe, “A ti n dibo l’Ekoo ninu egbe oselu PDP, ibo ote yii, ipo eyin patapata ni egbe oselu PDP wa. Okunrin ti a si fa kale ko dije dupo loruko egbe wa gan-an lo koba wa.
Okunrin oloselu yii fi kun un wi pe, “Gbogbo eto to ye ki won se fun awon asoju egbe (Agents) lagbegbe Apapa, ti won maa sise pata ni won ko ri nnkankan gba.
O fi kun un pe, “Lojiji la gbo pe EFCC ti mu Jimi Agbaje, iyen loru ojo Fraide mojumo ojo idibo. Bi mo se gbo oro yen ni mo ti fa foonu mi yo lati wo ori Naira land atawon eka iroyin mi-in, ti mo mo pe, to ba je bee ni, lojuese ni won maa sare gbe e. Nigba ti ko ti si iroyin yen nibe, lojuese ni mo ti mo pe iro gbaa ni, jibiti ni won fe fi oro yen lu wa.
“Isele yen gan-an ko sai koba gbogbo irin to ye ka rin, nitori gbogbo awon to ye ki won soju egbe, paapaa lagbegbe Apapa nibi, to ye ki won ba wa mojuto bi idibo se n lo, ni  oro ko ri ba a se fe, boro se di radarada niyen, bee ni esi ibo ti o jade, ekun lo ku ti a ko sun lojo yen.
“Kani Jimi Agbaje to je oludije fun ipo gomina ba se ohun to ye ko se ni, alubole ti egbe oselu APC lu egbe wa, paapaa  ni agbegbe Apapa ti Jimi n soju fun ko ni i waye, abamo nla ni o, wi pe a lo iru okunrin yen loruko egbe wa, nitori ko bikita ko fidi remi, abi kin ni ka ti pe ti oludije to n sare ki eni ti won jo figagbaga ku oriire lai bikita ipo ti egbe maa wa lori abajade esi ibo ohun.”
Sa o, oludije fun egbe oselu PDP, Ogbeni Jimi Agbaje ti pe Babajide Sanwo-Olu ni deede aago meje koja iseju die lati ki i ku oriire, bo tile je pe inu awon omo egbe oselu PDP kan ko dun si i, nitori owo ti won lo ye ko gbe jade to ko ti ko ko fun won, ti won si se bee fidi remi, paapaa lagbegbe ibi toun gan-an ti jade, iyen Apapa.

Post a Comment

0 Comments