GBAJUMO

NITORI TI AKALA JE OMO OGBOMOSO, WON NI YOO SORO LATI KOJU OLUDIJE APC * N LOUN NAA BA TELE BUHARI LO PATAPATA


Laipe yii nipinle Oyo lawon egbe oselu lorisirisi ko ara won jo, lati sasaro lori bi won yoo se jumo sise po lati koju egbe oselu to wa nipo soorun ale, iyen APC bi eto idibo gomina se n sunmo etile.
Bo tile je pe o fe ma si egbe oselu ti ko si nibi ipade ohun lojo naa, sibe won ko fenu oro jona lori eyikeyi ti won fe tele laarin PDP ati APC ti won je alenu-loro laarin awon egbe oselu to n dije nipinle ohun.
Lara awon egbe oselu to wa nibi ipade ohun lojo naa niwonyi; Action Democratic Party (ADP), African Democratic Congress (ADC), People’s Democratic Party (PDP) ati Zenith Labour Party (ZLP). Bi won se po to niye, sibe won ko so pe egbe bayii pato lawon yoo tele.
Sa o, lojiji ni iroyin gba igboro wi pe Otunba Adebayo Alao Akala to n dije loruko egbe oselu Action Democratic Party, iyen ADP ti kuro ninu idije ohun, ati pe Adebayo Adelabu, eni to n dije loruko egbe oselu APC lo fe sise fun bayii.
Otunba Christopher Alao Akala gan-an ko je ki won gbe oro ohun kiri jinna to fi bo sita lati salaye ohun to mu un gbe igbese ohun.
Ninu alaye e lo ti so pe, “Omo egbe oselu ADP ni mi, bee mi o fi egbe oselu ohun sile rara, sugbon mo setan lati sise fun egbe oselu APC, ti a o si fi ibo gbe Adebayo Adelabu wole, lojo kesan-an osu yii.
“Ohun to foju han ni pe emi gan an leni to se agbateru ipade ajumose to waye laarin awon egbe oloselu orisirisi nipinle Oyo lati le koju egbe oselu APC to n sejoba lowo. Nibe naa lati pinnu lati fi Seneto Raheed Adewolu Ladoja, ti egbe oselu Zenith Labour Party; eni ti se oga mi nidii oselu; gege bi eni ti yoo je abenugan nibi ipade ohun.
 “Bi eyi ti n lo lowo, asiko igba naa ni mo gba ipe latodo Aare Muhammed Buhari. Ipade ti mo si ba Aare se ni won ti be mi wi pe ki n jowo sise fun egbe oselu APC ki oludije egbe naa, Adebayo Adelabu le wole sipo gomina. Mo ni ki won fun mi ni ojo meji lati lo jiroro pelu awon oloselu akegbe mi nile.”
Alao Akala te siwaju pe, “Nigba ti awa egbe oselu orisirisi nipinle Oyo tun pade lati te siwaju lori ijiroro wa lori egbe ti a o gbarukuti gan-an, nibe gan ni Oloye Rashid Adewolu Ladoja ti so fun mi loju gbogbo awon oludije yooku wi pe mi o si ninu e ni ti awon egbe oselu to wa nibi ipade ohun le panupo ti siwaju lati koju egbe oselu APC fun ipo gomina nipinle Oyo nitori ilu ti mo ti wa; iyen Ogbomoso.
“Gege bi won se so lojo naa, won ni, “Eni ta a fe ko koju oludije egbe oselu APC ninu ibo yii gbodo je oludije to ba wa lati ilu Ibadan, nitori omo Ibadan ni Bayo Adelabu n se, eni ti yoo si ba a fa a daadaa gbodo je omobibi ilu Ibadan, ki i se iwo omo Ogbomoso.” Pelu oro ti won so yii, nibe gan-an lo ti ye mi wi pe ilu ti mo ti wa nipinle Oyo gan-an ni ese nla ti mo se, ti mi o fi le gbiyanju lati se gomina.
“Pelu aidaa ti won se fun mi yii, ohun gan-an lo mu mi pinnu lati ba awon eeyan mi nidii oselu soro, paapaa awon akegbe mi ninu egbe oselu ADP; ti a si jo panupo lati sise fun egbe oselu APC gege bi Aare Muhammed Buhari ti fe.
“Ni bayii, emi Otunba Christopher Adebayo Alao-Akala, eni to n dije dupo gomina ninu egbe oselu Action Democratic Party (ADP), ti pinnu lati sise papo pelu egbe oselu All Progressives Congress (APC), lati je ki Ogbeni Adebayo Adekola Adelabu jawe olubori ninu idibo gomina to maa waye lojo kesan-an osu keta odun yii. Bee gege ni mo setan lati gbarukuti gbogbo awon omo egbe oselu ADP ti won n dije fun ipo asofin nipinle Oyo ki won le jawe olubori.”
Sa o, Akala ti so pe oun ko fi egbe oselu ADP sile, ati pe gbogbo awon omo egbe oselu ADP ti won n dije lati je omo ile igbimo asofin Oyo loun wa leyin won gbagba, bo tile je pe oun ko ni i lo fun ipo gomina mo ni toun.”
O ni, ohun to foju han ni wi pe ki i se ilu Ogbomoso ti oun ti wa nikan ni egbe oselu ADP ti fidi mule, o ni kaakiri ipinle Oyo ni, paapaa lawon agbegbe bii Ibadan, Ibarapa, Oke-Ogun ati ilu Oyo gan-an.



Post a Comment

0 Comments