O jo pe Obasanjo si ni Buhari sinu gidigidi, okunrin
ajagunfeyinti omo Owu nipinle Ogun yii ko gba ti Buhari ati ijoba APC mo o, bee
ni baba naa ko foro ohun bo rara.
Boya eyin naa ko ti i gbo ohun ti Obasanjo tun wi… o ya e je
ki n salaye e fun yin daadaa. Baba Iyabo ti so pe, bi igbimo to n gbo ejo lori
eto idibo se so pe Seneto Ademola Adeleke, iyen okunrin onijo ara yen lo wole ipo
gomina nipinle Osun gan an lo dara ju,
Ebora Owu fi kun un pe, bi igbimo ohun se so pe eru lawon
Isiaka Oyetola atawon Aregbesola fi gba ibukun, ati pe nise ni won gbodo fi ipo
ohun sile ni kia lo dara ju. Obasanjo ti so pe idajo yen dun mo oun ninu daadaa
o, nitori eru buruku ti ko ni oruko mi-in ni won se l’Osun.
Bakan naa lo tun gbe oriyin nla fun igbimo ohun, to si so pe,
ni tododo, awon eeyan kan si wa lorile-ede yii ti a le fokan tan daadaa, toro
ba di ka sododo.
Ko tan sibe o, o ti ni olubi, eni esu ati abani-layo-je ni enikeni
to ba so pe bi Atiku se lo sile-ejo yen ko dara. O ni bi oun ko tie fe soro tele,
nitori ti oro ohun ti wa nile-ejo, sibe oun yoo soro bayii, nitori pe ole
buruku ni won fi ibo ohun ja Atiku ati egbe oselu e.
Obasanjo ti soro ranse lati Dubai o, bo tile je pe awon kan
n so wi pe ki baba naa rora, sibe Ebora Owu ti so pe, igba ni won n pa o,
enikan ki i pawo, bee leeyan kan bayii ko le pa ohun mo agogo toun lenu…ohun ti
ijoba yii yoo se fun Obasanjo, oju ree; iran ree.
0 Comments