Onarebu Razak Atunwa to dije dupo gomina loruko egbe oselu PDP nipinle
Kwara ti ki omo egbe oselu APC, Alhaji AbdulRahman AbdulRazaq to jawe olubori
ku oriire.
Ninu oro to fi sita naa lo ti dupe lowo egbe oselu PDP to dije
loruko e, bee lo tun dupe lowo awon asaaju egbe naa lori aduroti won.
Siwaju si i, o ti kan saara si gbogbo omo egbe oselu naa nipinle
Kwara fun ise takuntakun ti won se bo tile je pe nise lo fidi remi ninu eto
idibo to waye lojo Satide to koja yii.
Atunwa ti ki AbdulRahman AbdulRazaq ku oriire, o si tun ro awon
eeyan Kwara lati maa ba ara won gbe pelu alaafia.
0 Comments