Bi awon omo Nigeria se n da owo, ti won n fowo sowo si
akaunti Baba Suwe lori bi ara okunrin alawada yii yoo se ya, lojiji ni iroyin
tun gbalu pe Ojo Arowosafe, eni tawon eeyan mo si Fadeyi Oloro naa wa lori
akete aisan, ati pe oun gan-an nilo iranlowo gidigidi.
General
Hospital to wa ni Ile-epo l’Ekoo ni okunrin onitiata yii wa bayii,
nibi to ti n gba itoju. Aisan kan ni won lo n se e, eyi to mu un maa rawo-rase
sawon omo Nigeria lati se oun looore ki aisan ohun ma ba pa oun lojiji.
Sa o, okan lara awon gbajumo osere, iyen Ibrahim Chatta naa
ti soro o, paapaa lori bi awon eeyan kan se n so kobakungbe oro si i lori ero
alatagba e, nibi to gbe aworan Ojo Arowosafe, iyen Fadeyi Oloro si.
Okunrin onitiata yii so pe, “Ohun ibanuje lo maa n je bi
awon eeyan se maa n soro odi si awa ti a je osere, ti a ba toro iranlowo fun
okan ninu wa to ba n se aisan. Ki i se pe awa gan-an ko ti gbiyanju lati ran
iru eni bee lowo, sugbon nigba ti ipa ba pin, tabi nigba mi-in ti a ba woye wi
pe, boya ti a ba ke gbajare sita, enikan le mo nipa ohun ti a le lo, ti ara iru
eni bee yoo fi ya.
“Loooto la n sise, ti a n gba owo, sugbon awa naa ni bukata,
bee lopo awon eeyan gan-an ki i je ki a gbadun latara muwa-muwa. Mo fe so fun u
yin wi pe, ida ogota (60%) ninu owo ti mo n gba lori ise ni mo maa fi n gbo bukata
awon eeyan lorisirisi, bere latori awon ta a jo se kekere, awon mi-in ninu awa
osere ti won ko ti i ga bii awa ti awon eeyan n ri bi irawo osere. Ida ogoji
(40%) pere yooku lemi naa fi n toju ara mi atawon ebi mi.”
Okunrin onitiata yii fi kun un pe, pupo ninu awon osere ti
nnkan n se ni won ki i fe ki won tie gbe awon si gbangba lori idaamu to ba won.
O ni, “Ohun ti omi-in maa n so ni pe, ohun to maa mu awon gba baara, awon ko
ko, ki irufe aisan ohun gba emi awon. O ni, ohun isoro lo maa n je fawon ti won
je gbajumo lati bo si gbangba toro owo tabi iranlowo nigba ti isoro aye ba de.”
Ibarahim Chatta so pe, pupo ninu awon osere nla nla ti won
ni isoro lasiko yii ni awon naa ti lo ola ati owo won fi gbo bukata opolopo
eeyan lasiko ti nnkan n senuure fun awon naa. O ti wa ro awon araalu wi pe ki
won ye fenu egan ba awon wi mo, nitori ko rorun fun pupo ninu awon osere bi won
se maa n wo won.
Lara ohun ti gbajumo osere yiik tun so pe o n mu ijakule ba
awon osere ni idaamu awon to maa n se ayederu ise won. O ni, loooto ni won n
foju olowo wo wa latari awon fiimu ti a n gbe jade, sugbon kinni kan ti opo
eeyan ko ranti ni pe awon ti won n se ayederu fiimu wa gan-an lo n koba pupo
ninu wa, ti awon eeyan to ye ki won wa nipo olowo oloro nla n sagbe iranwo lojo
isoro.”
Ibrahim Chatta ti wa ro awon eeyan wi pe, enikeni to ba
setan iranlowo ko se e nitori Olorun, ki enikeni ma se ko oro kobakungbe sori
ero alatagba oun.
0 Comments