GBAJUMO

AARE ONAKAKANFO, IBA GANI FE SAYEYE OJOOBI L’EKOO *WON NI PEPEYE YOO PON OMO

Gbogbo eto lo ti pari bayii lori ayeye ojoobi odun mokandinlaadota (49) ti Aare Onakakanfo ile Yoruba, Iba Gani Abiodun Adams fe se laipe yii.
Gbongan nla Times Square, Event Centre, n’Ikeja, l’Ekoo layeye pataki yii yoo ti waye, nibi ti awon lade-lade-loye-loye yoo ti peju, tie se yoo pele paapaa lati seye nla fun akoni omo Yoruba yii.
Ninu atejade ti oluranlowo eto iroyin fun Aare Onakakanfo ile Yoruba fi sowo si wa, Alhaji Kehinde Aderemi; lo ti so pe, “Ayeye yii maa larinrin, bee ni gbongbn yoo kan si i pelu. Ayeye odun mokandinlaadota ni Aare Iba
Gani Abiodun Ige Adams fe se. Gbogbo eto pata lo si ti to. A fe ba asaaju wa yo, a fe ba olori wa seye nla, bee lawon ebi, ara, ore, egbe OPC ati OPU lapapo atawon ojulumo ti n mura gidigidi lati peju pese sibi ayeye nla ohun.”
O fi kun un wi pe, Gbogbo eeyan pata la pe o, eyin ojulowo omo Yoruba, e wa e je ka jo seye nla fun olori wa. Ojo ohun n sunmo, bee ni gbogbo eto lo n to, ti a n mura ketiketi lati ba oloriire omo Yoruba yo, ati pe ayeye nla ti yoo mi ilu titi lodun yii ni. A n reti yin o, awa paapaa naa n mura nnkan alejo sile daadaa.”
Bi Iba Gani Adams ti n se n palemo lati sayeye odun mokandinlaadota (49) yii, bee la gba a ladura wi pe, aadota odun ti yoo waye lodun to n bo yoo ba Aare Onakakanfo ile Yoruba ninu owo, ola, alaafia to peye ati alekun imo ati oye repete. Igba ile Iba ko ni i fo, awo ile Aare Onakakanfo ko ni i pe din, b’odun Gani Adams ba ti kodun, peregun Iba a maa mawo tutu bo wa saye ni. MAGASINNI ALORE ki Aare Onakakanfo ku odun oooo…a seyi samodun…a samodun…somiiran!


Post a Comment

0 Comments