Abi e o ri nnkan, won si fi aye han oga asobode kan laipe yii.
Abba Abubakar ni won pe oga asobode ohun. Lenu ise lo wa ti awon oyin fi kolu u, irufe isele ohun si fe jo agbosogbanu paapaa lode asiko yii fawon eeyan ti ko ba gbo o ri wi pe won a maa ran oyin si ni.
Adugbo kan ti won n pe ni Ashipa lojuna Eko si Badagry nisele ohun ti waye lojo Isegun Tusde to koja.
Ileese asobode ti kede iku e, bee ni won ti sapejuwe oloogbe ohun gege bi eso agbofinro nileese ahode ti kii fise e sere, to si ku senuuse.
Omo ipinle Yobe ni won e, baale ile ni, bee lo tun sabiyamo paapaa.
0 Comments