Tusde ojo Isegun, iyen ojo ketalelogun osu yii ni Wolii Morenikeji
Adeleke, eni tawon eeyan tun mo si Egbin Orun yoo se ayeye odun kan ti ori oke
Egbin Orun ti bere ise iyanu Olorun niluu Ifo, ipinle Ogun.
Bee gege lo tun so pe gbogbo eto ti pari lori rekoodu tuntun,
Aanu Oluwa ti oun yoo gbe jade laipe yii, Ileese Epsalum Movies Production Ltd
ni yoo ta rekoodu tuntun ohun.
Morenikeji Adeleke so pe, “Itan iriri aye mi lo kun inu
rekoodu tuntun yii foofo, bee ni yoo je atona ati awokose pelu ariko-gbon nla
fun gbogbo eni to ba ni in lowo.
“Nigba kan, emi ti e n wo yii, omo iberu ni won maa n pe mi,
ko seni to fe ni ohunkohun lati ba mi se, bee omo Iberu tawon eeyan n sa fun,
ti won pa ti nigba kan ana lo di Egbin Orun bayii, ti awon eeyan n ri ise iyanu
Olorun latara e. Ti o si n kede ihinere nipa Oluwa ati ijoba orun to ti pese
sile fun gbogbo eni to ba gba a gbo.”
Egbin Orun fi kun oro e wi pe, lara iriri ti oun ko le
gbagbe boro, ni bi iya to bi oun se n gbe oun se agbe kiri, sugbon ti oro ohun
pada ni itumo nla nigbeyin oro bayii.”
Rekoodu tuntun e yii, nibe gan-an lo ti tu gbogbo perepere
asiri ti enikeni ko mo nipa e, bee lo ti fidi e mule wi pe, gbogbo eeyan pata
lo ye ki won ni orin emi tuntun yii lowo, nitori anfaani nla ti yoo se fun
tomode-tagba. O ni, “Orin adura ni a ko jo sinu e, bee lo tun kun foofo fun
iriri ti omo eniyan gbodo maa lo lati fi gbe aye Kristeni rere.”
Siwaju si i, o ti so pe, “O se pataki ki a fi emi imoore han
si Olorun oba lori ise iyanu to n se lori oke adura Egbin Orun niluu Ifo
nipinle Ogun. Pupo ninu awon ti won n woju Olodumare lo ti saanu fun, ti awon
to n wa
itusile si ti gba idande, ti aye won ko si ri bakan naa mo. Ayeye odun
kan wa ti a fe se, ohun ta a fi se akori e ni: OLORUN AANU MI Ninu soosi Ori
Oke Egbin Orun, to wa ni Pastor Adebayo Str., Sojuolu Alameda niluu, Ifo,
ipilnle Ogun ni yoo ti waye.”
.
1 Comments
Very nice God we continue bless
ReplyDelete