Gbogbo eto lo ti pari lori
waasi ita gbangba ti awon ololufe gbajumo olorin Islam ni; RUQOYAH GAWAT FANS
CLUB fe se lasiko aawe Ramadan; ti yoo bere laipe yii.
Ninu atejade to te wa lowo ni
won ti fidi e mule wi pe, “Lojo kokadinlogun osu karun-un ni eto ohun yoo waye
gege bi a se maa n se e lodoodun.”
Egbe yii te siwaju wi pe, “Ohun
pataki ti a maa n se lasiko waasi ita gbangba yii ni lati pe ipe si oju ona
Islam, lati fi Islam han gege bi esin to ni opo oore ninu, ti Olorun si yonu si
julo. Lodun yii, oore nla lawon eeyan yoo ba pade nibi waasi osu Ramadan ti a
maa n se yii; nitori onimo nla ni yoo se waasi fawon eeyan, bee lorisirisi eto
tun ti wa nile gege bi a se maa n se lodoodun.”
Waasi ita gbangba yii ni yoo je
eleeketa iru e ti egbe ololufe Ruoqoyat Gawat Fans Club yoo se. Ninu ogba Kosofe
Local Government, ladojuko Police station, Ogudu l’Ekoo ni eto ohun yoo tio
waye, eyi ti yoo bere laago mewaa aaro. Sheik Ibraheem Saheed Olawunmi, eni
tawon eeyan tun mo si Baba l’Orile ni yoo fi oro Olorun ba awon eeyan soro.
Alhaja Ruqoyah Olabisi Aduke
Oyefeso, eni tawon eeyan tun mo si Omo Oloore je okan pataki ninu awon olorin
Musulumi ti won n se daadaa lawujo loni-in, kaakiri ni won ti n gbo rekoodu
orin e, yala eyi to da se ni, tabi eyi ti oun atawon elegbe e ba jo se.
Opolopo rekoodu lo ti gbe jade,
bee lo ti gba orisirisi ami eye nile yii ati loke okun. Lara e ni Sheika of
Music; Amira Dhakirat, Habibatul Alamin; Amira Shuarai; Queen of Music ati bee
bee lo.
Ninu oro e lo ti so pe, “Osu
aanu ni osu Ramadan, osu ike ni, bee lo tun kun fun ige paapaa. Fun idi eyi,
ohun to ye gbogbo Musulumi aye pata ni ka saanu ara wa, loooto Olorun lo ni ike
ati ige lodo, sugbon eyi ti awa naa ba le se fun omolakeji, e je ka se e, ki
Olorun je ki a ri oore ayo gba nibe.
"Ona kan pataki ti awa naa nigbgagbo lati fi da si eto Olorun yii ni agbekale waasi ita gbangba, eyi ti a maa n se lodoodun. Yato si waasi, ti awon eeyan yoo wa gbo, orisirisi eto to le se awon eeyan lanfaani lo maa waye lojo naa."
0 Comments