Okunrin
omo Nigeria kan, Samuel Nkennaya, eni ti se omo odun metalelogoji (34) ti pade
iku ojiji lorile-ede South Africa, bi won ti se kolu oun ati eni keji e, ti won
ro pe gbomogbomo ni won.
Yato
si Samuel to ku yii, bakan naan ni okunrin kan, Chinonso Nwudo toun naa je omo
Ngeria wa lese kan aye se kan orun losbitu nibi to ti n gba itoju. Awon eeyan
kan ni won kolu won, esun ti won si fi kan won ni pe, nise ni won ji omo odun
mefa kan, Chinonye gbe.
Ogbeni
Victor Ayanfe-Oyebanjo, akowe agba fun agbegbe Mpumalanga Province, fawon omo
Nigeria ti won n gbe ni South Africa lo so oro ohun di mimo fun ileese News
Agency of Nigeria (NAN) loni-in ojo Isegun, Tusde.
O
ni, ohun ti ko ye awon to kolu won yii ni wi pe, omo Nwudo ni Chinonye n se, ki
i se pe won ji omo naa gbe.
O
ni, ohun to sele ni pe,“Nwudo ti se baba omo naa lo mu un lo sodo ore e,
Nkennaya ti won ti dana sun yii ni agbegbe kan ti won n pe ni White River town lowo
irole ojo ketadinlogbon osu yii. Bi won se debe ni Nwodu ati ore e ba gba ile ijeun
KFC lo lati lo ra ounje fun omo odun mefa yii.”
Okunrin
yii te siwaju pe bi won ti ra ounje ohun tan, nise lawon eeyan kan ti won wa
nibe bere si pariwo wi pe gbomogbomo lawon okunrin mejeeji, nitori omo kekere
omo odun mefa ti won ri pelu won, lai mo pe okan ninu won lo bi i.
Nibi
ti wo ti n lu won ni Nwudo ti n pariwo wi pe omo oun ni, ki won pe iyawo oun to
je omo orile-ede South Africa lati fidi e mule. Ariwo to n pa a yii ni ko je ki
won lu u pa, nitori okan ninu awon eeyan ohun pe iyawo e loooto, tiyen si so pe
okunrin yii lo ni omo ohun.
Bo
tile je pe awon olopaa ti won rin sasiko naa pelu awon eni ti ko won yo lojo
naa, sugbon ore e Nkennaya ba isele naa lo ni tie, osibitu ni won so pe o ku si,
nigba ti Nwudo si n gba itoju losibitu ni tie.
Saaju
asiko yii lopo omo Nigeria ti riku ojiji he, bi won ti se n dana sun won, bee
ni won n fi iku gbona orisirisi pa won, ti orile-ede naa si gbona girigiri fun
won.
0 Comments