GBAJUMO

O MA SE O: WON SI FE DA NNKAN RU MO GOMINA YII LOWO

Awon ara Eko n binu o, Tirela repete to wa loju titi lati Fadeyi titi de Apapa lo fa a o. Won lo jo pe aja oyinbo ni ijoba Akinwunmi Ambode l’Ekoo ko le sode debii pe yoo bu omo eranko je.
Won ni iya buruku ti won fi n je awon eeyan l'Ekoo, o jo pe ara awon ti fe ko o bijoba ko ba si wa ojuutu si i, gbadogbado yoo gbowo agbado lowo awon atawon eeyan toro ohun kan laipe yii.
Enikan to ba wa soro pelu itara tie so pe; bi eni n gbe ara ilu senu janduku loro ohun ri o, nitori nise lawon janduku n lo anfaani wolulolu oko yii lati fi jale, bi won se n gba foonu ni won n fibon atawon ohun ose mi-in ja awon eeyan lole.
Bakan naa ni won tun fi kun un pe, owo awon onitirela paapaa ko mo, bee ni ijoba gbodo wa nnkan se si i.

Te o ba gbagbe, lojo ti Buhari n bo l'Ekoo, lojuese lawon onitirela yii palemo ara won kuro loju popo, sugbon ni bayii, gadigadi ni gbogbo titi ohun tun ti di, bere lati Fadeyi. titi de Ojuelegba to fi de Iponri, bee ni Costain titi de Ijora lo sinu Apapa ko rorun, ti ori biriji Eko naa ko si ti di ona tooro fawon moto keekeeke lati maa gba, bee ni gbogbo Ijora olopaa paapaa ti di woluwopo pada.
Ibeere tawon eeyan n bi ijoba Ambode l'Ekoo ni pe se enu e ko ka won ni abi awon onimoto gan-an lo fe mo on mo ba ijoba Eko je mo on lowo...
Se oro ko maa ba oro bo bayii?


Post a Comment

0 Comments