GBAJUMO

OKU REPETE NILE HAUSA, IJA BURUKU NI WON LO BE SILE NIBE


Wahala nla kan la gbo pe o ti be sile bayii laarin awon eya kan ti won n pe ni Jukun atawon Tiv nipinle Taraba ati Benue, o ti le ni eeyan mewaa ti won so pe won ti ku bayii.
Oni Ojobo yii naa ni won so pe ija eleya-meya yii bere, bi won se n pa ara won, bee ni won n dana sunle, ti oro si ti di bo o lo o yago.
Enikan to ba awon oniroyin soro salaye wi pe, bii oku eeyan meje ni won ti ko jade ninu igbo  lagbegbe kan ti won n pe ni Tse Atsenge.
Bi awon obinrin ti won gbe omo pon seyin se n sare, ti won n subu asubulebu, bee lawon omo keekeeke paapaa naa n wa gbogbo ona lati bo lowo iku ojiji ohun.
Gomina ipinle Benue, Samuel Ortom ti pe ipe fun alaafia, bee lo ro awon eso agbofinro lati sapa lori bi won yoo se da alaafia pada si agbegbe ti ija buruku yii ti n sele.


Post a Comment

0 Comments