GBAJUMO

BOLA DISCOVERY, OLORIN EMI FE PE APERO NLA *AWON OJISE OLORUN OBINRIN ATAWON AKOSEMOSE LO MAA WA NIBE

Gbajumo olorin emi nni, Efanjeliisi Bolanle Oladapo, eni tawon eeyan tun mo si Bola Discovery ti so pe gbogbo eto lo ti fe pari lori apero nla kan ti oun yoo pe, nibi ti awon ojise Olorun lobinrin atawon akosemose obinrin yoo ti pade lati josin papo fun Olorun.
Laipe yii ni gbajumo olorin emi yii seto nla kan, iyen lojo Ajinde, Monde to koja lohun-un, nibi to se akanse eto lati fi emi imoore han si Olorun fun ayeye ogoji odun to pe laye, bee lo tun se ifilole rekoodu tuntun lojo naa.
Ni bayii, o ti so pe laipe yii lawon eeyan yoo lanfaani lati gbo orin tuntun ohun lori orisirisi ero alatagba.
O fi kun un wi pe, rekoodu ohun yoo mu ilosiwaju nla ba gbogbo awon omoleyin Kristi ati gbogbo eniyan to ba nifee si Olorun ati ise ihinrere re.
   Nigba to n salaye bo se bere lo so bayii wi pe, “Noosi olutoju alaisan ni mi, akosemose gidi paapaaa, ti mo tun ni iwe eri aladanla, iyen Masters in Social Works, eyi to tumo si ise itoju, bakan naa ni mo tun je okan lara awon osise nileese Leah Medical Centre, okan lara eka ajo kan ti ki i se tijoba, iyen Leah foundation; nibi ti won ti maa n se idanilekoo ati amojuto jejere omu ati eyi to maa n mu awon obinrin loju ara.
“Nile ijosin wa gan-an ni mo ti bere orin, nise ni mo darapo mo egbe akorin, bee mo kere pupo nigba yen, mi o ju omo odun mefa pere lo, sugbon loni-in, Oluwa ti so mi di okan lara awon ayanfe e to n kede ise iranse re. Lara ohun meremere ti Olorun ti lo mi fun nidii ise iranse yii niwonyi; mo ti saaju awon akorin lati korin yin Olorun ni gbagede nla, nibi ti a ti se ipago-orin iyin, bee ni mo ti saaju awon eeyan daadaa lawon ipade ipago nla nla ti won gbe kale lati fi jihin ise rere Oluwa.”
Rekoodu orin nla kan ni Bola Discovery ti se, bee lo ni awon keekeeke mi-in ti ko to odidi rekoodu to ti se pelu, ti awon eeyan si n gbo o kaakiri nile yii ati loke okun.
O fi kun oro e wi pe, ise ti fe pari lori rekoodu keji ti oun n se lowo. Bee lo ti so pe, “Ti won ba n so nipa eni ti mo mu gege bi awokose, Jesu Kristi ni awokose pataki ti mo ni o, bee ni mo tun maa n lo gbogbo awon eeyan mimo ti Bibeli, iwe iyin ati ogo daruko gege bi awokose mi. Bakan naa ni mo tun ni eeyan pataki kan ti isesi re wu mi pupo, iyen Diakoni-obinrin, Omolewa Ahmed.”
Te o ba gbagbe, lojo Ajinde Monde, lasiko ayeye ajinde ni Efanjeliisi yii ko awon eeyan jo nibi to ti se akanse eto iyinlogo to pe akole e ni YAHDAH, ohun ti Bola Discovery feto ohun sori ni idupe fun Olorun, paapaa bo ti se se ayeye ogoji odun laye.
Ni bayii, o ti so pe ohun nla kan tun n bo laipe yii, nibi ti oun yoo ti ko awon eeyan nla nla jo, iyen awon obinrin ti won je akosemose ati awon to je ojise Olorun, nibi ti apero pataki ati iyinlogo yoo ti waye



Post a Comment

0 Comments