GBAJUMO

NITORI SENETO ADELEKE TAWON OLOPAA JU SATIMOLE, EGBE OSELU PDP N BINU O


Egbe oselu PDP ti bu enu ate lu bi ileese olopaa orile-ede yii se mu Seneto Ademola Adeleke, ti won si ju u si atimole won.
Egbe naa ti so pe, ohunkohun ko gbodo se e, ati pe bi won se mu okunrin oloselu naa, okan awon ko bale, nitori o see se ki won fun un ni majele je.
Loni-in ojo Aje nileese olopaa mu Seneto Ademola Adeleke lasiko ti won ranse si i wi pe ko yoju si ofiisi awon l’Abuja.
Okan lara awon ololufe e so pe, “Lasiko igba to wa nibe naa ni won so oro ohun di bami-in mo on lowo, ti won si fesun kan an wi pe o yi iwe esi idanwo iwe mewaa to n gbe kiri ni. Ke e si maa wo o, oro esi idanwo yii, ile-ejo giga kan ti n gbo ejo lori e lowo, ki lo tun wa mu awon olopaa ti won tun siwe kan esun ti ile ejo kan ti n gbo oro lori e lowo. Ete ati ogbon buruku ni won n da, won ko fe ki Adeleke gba eto e lowo awon to feru gba ibukun ni, bee imoran won ko le se, oun gan-an ni awon eeyan ipinle Osun dibo yan, o si di dandan ko dari ipinle ohun, otubante lasan ni ete awon ota.”
Sa o, ileese olopaa ti so pe loooto lokunrin oloselu naa wa lahamo awon, ati pe lola gan an lawon yoo gbe e lo sile ejo lori awon esun iwa odaran kan ti won fi kan an.
Bee ni PDP naa n pariwo, ti won n so pe, ohunohun ko gbdo se e, ati pe eera kan bayii ko gbodo ra a pelu, nitori iya lasan ni won fe fi je e, bee nitori ti igbimo to n gbo esun lori eru to ba sele lasiko ibo, ti awon yen da a lare gan-an lo mu awon alatako maa wa isubu okunrin ohun.








Post a Comment

0 Comments