GBAJUMO

E WO OKUNRIN HAUSA YII, AWON OMO KEEKEEKE LO MAA N BE LORI L'ABUJA * O NIYE OWO TO N TA WON


Owo olopaa ti te okunrin Hausa kan, omo odun meijilelogun ni, Mustapha Aliyu loruko e n je, bee awon omo keekeeke lo maa n be lori niluu Abuja, to si maa n ta a.
Ohun ta a gbo ni pe, o ti di omo keekeeke merin to ti ge lori bayii lawon ilu kan legbee Abuja, okunrin meta obinrin kan lawon omo ohun n se.
Ohun ti Mustapha so fawon olopaa ni pe, egberun lona aadosan-an (N170,000) naira ni won maa n ra ori okunrin lowo oun, nigba ti awon to maa n ra ori obinrin lowo oun maa n san egberun lona ogojo naira (N160,000).
Omo karun-un lo fe lo be lori ki owo awon olopaa too te e. Ninu oro oga olopaa nigba to n ba awon oniroyin soro lo fidi e mule wi pe, ori omo odun meta kan, ti oruko e n je Usman Awalu, omo Fulani; tawon obi e n gbe abule Leleyi ni won ka mo on lowo.  
Mustapha ti jewo wi pe loooto loun huwa odaran ohun. Ninu alaye e fawon olopaa lori bo se di agbanipa, to n pa awon omo keekeeke kiri lo ti so pe, owo kan ti oun nilo lati fi te siwaju ninu eko oun lo sun oun de idi ise buruku yii.
O ni, “Okunrin kan ti oruko e n je Mallam Yahaya ni mo lo ba, ti mo so isoro mi fun un. Lojo naa; nise lo ra iresi fun mi, bee lo tun ni ki n fi Maltina kan le e. Leyin ti mo je ounje yen tan, mo ri i pe mi o le soro daadaa mo, bee ni mi o mo ohunkohun kankan mo. Mallam yen fun mi ni oogun kan, o ni ti mo ba ti ri omo kekere kan to n sere kiri, ki n fi kan an, ko ni i le se ohunkohun.
“Loooto ni mo ri omo kan, bi mo se fi kan an niyen, ti ko le se ohunkohun. Bo se di pe mo ge e lori niyen, ti mo si ta a ni egberun lona ogojo naira. Omo karun-un ti mo fe lo be lori ni won ka mo mi lowo. Bi mo se dero ibi yii niyen.”
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo, eni to ran Mustapha nise ti na papa bora. Bee lowo awon olopaa ko ti i te e.

Post a Comment

0 Comments