GBAJUMO

KIN NI IWO MO NIPA AMINAT BABALOLA, OMOTAYEBI OLORIN MUSULUMI?

Ti a ba n so nipa gbajumo olorin Musulumi to gbajugbaja loni-in, ipo iwaju ni Aminat Folasade Babalola-Balogun wa, eni tawon eeyan tun mo si Omotayebi.
Laipe yii ni obinrin naa se ojoobi, bo ti se ko awon ololufe e lenu jo, bee naa lo lo si ile awon omo alainiyaa; to si lo se ohun to lagbara fun won lati fi dupe lowo Olorun to tun da a si, to fi ri odun tuntun.
Eyi ni ohun kan tabi mi-in ti opo eeyan ko mo nipa e:
·       Iyawo ile ni, ti Olorun si fun un lawon omo alalubarika
·       Olorin Musulumi to kewu daadaa, to si gbo esin Islam ye yekeyeke lobinrin naa n se.
·       Musulumi daadaa ni, ti imura ati isesi e je awokose nla fawon eeyan, ti won si feran lati maa se pupo ninu ohun ti Omotayebi ba se
·        Bakan naa lo je ogunna gbongbo laarin awon olorin Musulumi ti orin won ki i se asadanu lawujo
·        Ninu awon olorin tabi osere ni Nigeria ti won ni awon eeyan to maa n kose lodo won, okan pataki ni Omotayebi n se, bee lo maa n sayeye ominira fun won pelu ati iwe eri to yaranti
·        Onisowo nla ni Omotayebi, nipa ka se karakata, egungun bii eyin sowon ninu ara.  
·        Fun opo eeyan ti ko mo on, olorin ni, osere ni, bee lo tun je ojulowo alaga iduro, ta a ba n so nipa ka dari eto igbeyawo pelu ka dari eto ayeye okan pataki ni.
·         Aminat Omotayebi gan an ni Amira fun gbogbo awon to n korin esin Islam, iyen ISMAN.
·         Ti won ba n so nipa olorin Musulumi to ni awon ololufee to po julo loni-in, asaaju ni, bee lawon ololufe e yii, OMOTAYEBI FANS CLUB se bebe lasiko aawe nigba ti won ko opolopo eru lo sile awon omo alainiyaa, ti won tun ko ounje, owo atawon ohun mi-in fawon opo.
·         Oye nla kan wa, Senior Advocate for Women Affairs, ilu Abidjan lorile-ede Cote D’Oveir lohun-un ni won ti fun un loye ohun. Won ni asaaju ni, ti a ba n so nipa awon to maa n ja fun obinrin.
·         Omoleyin Alhaji Qmardeen Ayeloyun ni, bee ni ko figba kan ye kuro leyin okunrin olorin Musulumi ohun ri.
·         Fawon eni ti ko ba mo, omoleyin Jesu, iyen Kristeni gidi ni mama to bi Tayebi n se. Iya naa lo bi i,  to to o, to si fi ona esin Islam mo on…
·       Lara ohun to so o di eeyan nla laarin awujo ni iwa omoluabi, bee ni ki i foju tenbelu awon ololufe e, eyi to mu un maa gberegejige si i.
Ki i se pe Tayebi kan se ojoobi e lasan o, bo ti se ya ile awon alainiyaa, bee lo nawo iranwo sawon  opo, to ni ki kaluku wa je ninu ohun rere ti Olorun fun oun. Nigba ti gbajumo olorin esin Islam yii naa yoo si soro, o ni, “Olorun ti ni ki a maa dupe, ti a ba si n so nipa awon to moore Olorun ninu aye won, mo dupe wi pe, emi naa moore o, nitori e gan-an ni mi o se ni pada ninu ohun gbogbo to ba je ti Olorun…bee ni mo seleri lati sin in ni gbogbo ojo aye mi…”


Post a Comment

0 Comments