GBAJUMO

MKO ABIOLA, OORE NLA KAN TI IJOBA BUHARI SE FUN OPO EMI TO BA JUNE 12 LO REE

Abiola ree, nibi to ti n dibo to gbe e wole lodun 1993

Bo tile je pe fun opo odun lawon ipinle kan nile Yoruba ti maa n sajayo ayajo ojo ti gbogbo omo orile-ede yii jade lopo yanturu lati dibo won fun Oloogbe MKO Abiola, iyen ojo kejila osu kefa odoodun, sibe eyi to waye lorile-ede yii loni-in yato, ti opo omo Nigeria si n sadura fun ijoba Buhari wi pe daradara gan-an lo se.
Se, o pe tawon eeyan ti n so pe ohun ti yoo letoo ni ti ijoba apapo ba le mu ojo ohun ni pataki, ki opo emi to ba isele June 12 lo; ma kan se bee segbe lori asan.
Ni kete ti ijoba Buhari ti bere igbese lori yiya ojo ohun soto, to si tun fun Oloogbe MKO Abiola ati Babagana Kingibe ti won jo dije dupo nigba naa ni oye nla, iyen GCFR, lawon eeyan ti n so pe, ohun daradara gan an ni ijoba APC labe akoso Muhammed Buhari fe se lori iranti MKO.
Ni kete tawon omo ile igbimo asofin paapaa ti fowo si i, toro ohun si ti di ase ni inu awon eeyan ti n dun n sikin, ti won si n so pe, dajudaju Abiola atawon mi-in ti won ba isele ohun lo, won ko ni i ku lasan.
Wọ́n bí Abiọla sí ìlú Abẹ́òkútà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn lọ́jọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹjọ ọdún 1937.
Abiọla ni ọmọ kẹtàlélógún ti bàbá rẹ̀ bi, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pe oun làkọ́koọ́ ọmọ ti o duro sayè, ti ko ku lomode. Idí rèé tí wọ́n fi sọ orúkọ rẹ̀ ní 'KÁṢÌMÁAWÒÓ', eléyìí tó túmọ̀ sí "ẹ jẹ́ kí á máa wò ó bóyá òun náà á ṣe bí àwọn ti ìṣáájú ti ṣe.” Orúkọ àbíkú ni orúkọ ọ̀hún. Nígbátí ó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ni àwọn òbí rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ọ́ ní Moshood.
Abiọla lọ sí ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ African Central School nìlúu Abẹ́òkútà. Gẹ́gẹ́ bíi ọmọ at'àpáta dìde; ó ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àgbẹ̀, lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà sì rèé, Abiọla a maa ṣẹ́ igi tà kí ó lè rí owó ilé ìwé rẹ̀ san.
Ó tẹ̀ síwájú ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ìwé B
Babagana Kingibe to fe se igbakejin e ree
aptist Boys High School, ní ìlú Abẹ́òkútà bákan náà. Àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ wà ní ilé ìwé ọ̀hún ni Olusegun Obasanjo àti àwọn mìíràn. Ní ọdún 1960, Abiọla gba Ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti owo ìjọba láti lọ kàwé ní University of Glasgow, ní United Kingdom. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ ìṣirò owó, ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀hún gb'oyè.
Ojú ò kúkú ní i rí arẹwà k'ó má ki i, Abiola pàápàá gbìyànjú nínú òwò abo.
Lára àwọn ìyàwó bàbá yìí ni a ti ri, Simbiat Atinukẹ Ṣoaga,  Kudirat Ọlayinka Adeyemi, Adebisi Ọlawunmi Ọṣin, Doyinsọla Abiọla Aboaba, Modupẹ Onitiri àti àwọn mìíràn.
 Bàbá yìí ṣabiyamọ pàápàá, gbogbo wọn ni wọ́n sì yàn tí wọ́n yanjú. Nínú wọn ni
Hafsat Abiola (olóṣèlú, ajàfẹ́tọ̀ọ́-'mọnìyàn), Dupsy Abiola (Agbẹjọ́rò, oníṣòwò), Kọ́lá Abiola, Lola Abiola-Edewor, Mumuni Abiola, Khafila Abiola àti àwọn mìíràn.
 Ààrẹ Abiola jẹ́ oníṣòwò, ó sì dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé iṣẹ́ sílẹ̀ ní ìlú Òyìnbó àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, lára wọn ni:  Abiola Bookshops, Abiola Farms, Wonder Bakeries, Concord Press, Concord Airlines, Summit Oil International Ltd, Habib Bank, Decca W.A. Ltd,
Abiola Football Club àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ẹlẹ́yinjú àánú ni Abiola, kò sì mọ owó kan la kì í fún ènìyàn. Abiola gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ribiribi ṣe jákèjádò orílẹ̀ èdè yii. Ó kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìwé, ilé ìwòsàn, Mọsalasi, ilé Ìjọsìn, ilé ìkówèépamọ́sí,ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ẹ̀rọ ìgbàlódé àti àwọn iṣẹ́ àkànṣe mìíràn.
Lojo ti Aare Buhari fun un nipo nla niyi
Abiola jẹ́ òye tó fẹ́rẹ̀ tó igba, láti ìlú tó tó bíi àádọ́rin jákèjádò ilẹ̀ Nàìjíríà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí àwọn ológun ti wà lórí ètò ìṣèjọba lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó di dandan fún Ààrẹ Ológun ìgbà náà, Ibrahim Babangida láti gbé ìṣàkóso fún ìjọba Alágbádá. Eléyìí ló mú Olóyè Abiola díje dupò Ààrẹ Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party (SDP), ó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò abẹ́lé tí ẹgbẹ́ náà ṣe.
Báyìí ni Abiola ṣe figagbága pẹ̀lú alátakò rẹ̀ tó wa nínú ẹgbẹ́ òṣèlú National Republican Convention (NRC), Alhaji Bashir Tofa, tó sì fi ìbò àkàìmọye mú ẹ̀yìn Tofa balẹ̀ lọ́jọ́ Kejìlá, oṣù kẹfà ọdún 1993.
Ìdìbò ọjọ́ náà ni àwọn àjọ àgbáyé sọ wí pé ó lọ ní ìrọ̀wọ́ ìrọsẹ̀ jùlọ, kò ní màkàrúrù nínú rárá títí di òní olónìí.
Ohun tó ṣe'ni láàánú ni pé Ààrẹ ológun ìgbà náà, Ibrahim Babangida wọ́ igi lé èsì ìdìbò ọ̀hún. Eléyìí sì fẹ́rẹ̀ dá ogun sílẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nígbà náà, pàápàá ní ilẹ̀ Yorùbá.
Babangida fi ìbẹ̀rùbojo gbé ìjọba sílẹ̀, ó sì fi Olóyè Earnest Shonekan sí ipò ìṣàkóso gẹ́gẹ́ bíi Olórí ìjọba Fìdí-hẹ. Ọjọ́ ò t'ọ́jọ́, oṣù ò t'óṣù tí ìjọba ológun mìíràn, èyí tí Ogágun Sani Abacha léwájú fún gba ìjọba lọ́wọ́ Shonekan ní ọdún 1993.
Ní ọdún 1994, Olóyè Abiola kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ní kété tí Abiola ṣe ìkéde yìí ni ìjọba Sani Abacha rán ikọ̀ ọlọ́pàá tó tó igba láti wá mú Abiola. Ẹ̀sùn tí wọ́n sì fi kàn án ni ẹ̀sùn ìṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Àpapọ̀.
Wọ́n mú Abiola, ó sì wà ní àhámọ́ fún ọdún mẹ́rin. Abiola kú ní ọjọ́ keje oṣù keje ọdún 1998, ọjọ́ yii gan-an ni wọ́n fẹ́ dá Abiola sílẹ̀ kúrò nínú ahamọ Abiola ni Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfo kẹrìnlá Gbogbo ilẹ̀ Yorùbá.
E je ka ki Aare Buhari wi pe  o seun
Lára àwọn ohun tí wọ́n fi pe'rí bàbá yìí lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni  Àyípadà ilé ìwé gbogbonìṣe ti ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògùn tó wà ní ìlú Abẹ́òkútà sí Moshood Abiola Polytechnic, àti Pápá ìṣeré t'ó wà ní Kútọ̀ sí MKO Abiola Stadium. Ère bàbá yìí sì wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní orílẹ̀ èdè yii.
Ní ọdún 2018, ìjọba Àpapọ̀ èyí tí Ààrẹ Mohammed Buhari léwájú fún, fi àmì ẹ̀yẹ tó ga jùlọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (G.C.F.R) dá òkú Abiola lọ́lá....
 Ni bayii. Aarẹ Buhari ti bu ọwọ lu iwe ofin pe,ki gbogbo ọjọ kejila ninu osu kẹfa ọdun maa jẹ ayajọ ọjọ isejọba awarawa ti oni yii si ni Akọkọ iru ẹ. ki Olodumare tẹ MKO si Afẹfẹ rere
Ki Odumare ọun si ba wa se atilẹyin fun Aarẹ Buhari ati gbogbo igbimọ isejọba rẹ....

Lati owoo: Ọba Fedeyangan

Post a Comment

0 Comments