Lola ojo
kejidinlogun osu kejo yii ni ilu
Ibadan maa gbalejo nla nibi ti awon
ebi Adesigbin ti maa se akanse
adura fidau fun mama won, Alhaja Afusat Aduke Adesigbin leyin odun
kan to doloogbe.
Ninu atejade to te wa lowo
ni won ti fidi e mule wi pe, lati London, Italy, ireland; America atawon orile-ede nla mi-in
kaakiri agbaye lawon eeyan ti maa
wa,
bee lawon to wa ni
Nigeria naa ko ni i gbeyin rara.
Gbongan
nla Lagelu Grammar School ni Lagelu Agugu n’Ibadan ni eto pataki yii yoo ti waye, bere lati aago
mewaa aaro si merin irole nibi ti awon
Alfa nla-nla yoo ti peju-pese lati sadura fun oloogbe ohun. Bee gege ni itoju
awon alejo yoo waye pelu ni gbagede ohun.
Ninu oro okan lara awon omo
oloogbe yii, Ogbeni Ademola Adesigbin lo ti sapejuwe mama naa gege bi abiyamo tooto,
to gbiyanju lati to awon omo e daadaa ki won le ni ojo ola to dara.
O ni, “Gege bi igbagbo awa Musulumi, ohun kan ti a le maa se fun
oku orun
wa; naa ni
iranti won pelu adura ati itore aanu loruko won. Iya wa se daadaa pupo, eni ti
a ko si le gbagbe laelae ni, ki Olorun tubo ba wa fi alijanna onidera ke won.”
Lara awon omo to gbeyin
mama naa niwonyi; Ismail Ademola Adesigbin; Morufat, Musbaudeen, Moruf,
Lateefah; Morufat, Idowu, Mutiu Ishola atawon ebi; ara, omo-omo ati bee bee lo.
0 Comments