Idirs okunrin to n se bii obinrin...oun niyi pelu omu laya e |
Oga gba nileese ijoba to n
ri si Asa ati isese, Otunba Olusegun Runsewe ni okunrin to n se bii obinrin yii, Bobrisky yaju si, ki oloju si too se e,
nise ni nnkan daru mo on lowo, toro si di bi bami-in mo on lowo bayii.
Ohun ta a gbo ni pe, lana-an
gan-an ni Bobrisky loun yoo pate ariya nla, nibi to ti fe ko awon tie jo lati
sayeye ojoobi, sugbon bo ti se n pete ariya yii lowo, bee lawon olopaa n so, bo
si ti se ku dede ki won bere inawo ohun lawon agbofinro yade, bi won se le awon
alabase e danu niyen o, ti won ni Bobrisky paapaa na papa bora, tawon eeyan ko
si mo ibi to gba lo.
Se ko too di asiko yii
lokunrin yii ti fenuko, nibi to ti n
hale wi pe ko si ohun kan bayii ti Otunba Olusegun Runsewe le se fun oun,
nitori pe awon to ju u lo daadaa lenu ise ijoba loun n ba tayo, ti oro ba di pe
eeyan n mo eeyan lawujo.
nigba to koko bere ree |
Ninu iwe iroyin oloyinbo kan,
iyen Vanguard ni Otunba Runsewe ti bu enu ate lu iwa ati isesi Bobrisky. O ni, asiko
ti to bayii fun ijoba lati tako iwa idojutini ti Bobrisky n ko ba awujo wa.
O ni, “Bobrisky
ti e n wo yen, idojuti nla gbaa lo je fun orile-ede wa. Ohun ti awon eeyan mo on mo tele ni pe, awon ipara
gbigbona tawon eeyan fi n bora lo koko fi bere, nigba to ya lo di pe, oun naa wa ogbon da si aya e, ti oun naa deni to ni omu, bee lo tun yo idi bombo bii obinrin, to n wa fi osi se ayo
kiri.
'‘Ti Bobrisky
ba n se iru iwa idojuti yii lawujo, to fi n pawo, bawo la se le ba awon odo orile-ede yii soro lati ma se
tele irufe iwa bee.? Loooto ni Bobrisky
ni eto, sugbon
iriu eto yii ki i se ohun to ba oju mu lawujo Nigeria.
Otunba Runsewe |
“Ki i se oun nikan lo n
hu iru wa yii, iru e po daadaa, sugbon
ki i se orile-ede yii ni won wa, kaakiri lawon orile-ede mi-in niru won wa. Ti a ba si ko, ti a ko gbe igbese to nipon lori oro Bobrisky,
ko sigba ti ko ni ko awon eeyan kan jo, ti won a maa je
iru aye ijekuje yii kiri, eyi to see se ko gbile ju bi a se lero lo.
“Ibanuje nla ni abajde
iru iwa idojuti yii yoo si je, abi nigba ti awon obi ba n pokunso, ti won n gbe
majele je nigba ti omo ti won fi gbogbo ojo aye toju ba n se bii Bobrisky, ti okunrin n se bii obinrin kaakiri.
“Ohun to wa nile yii,
ki i se ere tabi awada, ohun aburu gbaa ni Bobrisky fe bere lorile-ede yii, bee
la gbodo gbogun ti i, ko too dohun ti apa ko ni i ka mo, ki a le ni ojo ola to
dara.
”Ise ti mo gba ni, lati
mojuto igbelaruge asa wa ati ise omoluabi lorile-ede yii. Bee ni yoo je ohun
to bu ni ku, ti mo ba dake lai fohun si osi ti okunrin yii n se, to so pe oun n
yo kiri.
Ati pe ta o ba tete gbe igbese, ko sigba ti awon omokunrin
naa ko ni i maa gbe igba asewo legbee titi.
”Laipe yii ni omo
orile-ede yii kan; gbajumo nla leni ti mo n yii, o sabewo si omo e niluu
oyinbo, iyanu nla lo je fun un nigba to ri i pe ibasepo okunrin si okunrin lomo
oun n se niluu oyinbo. Isele to ri yii ba a lojiji, lojuese lasian kolu u, ori keke
ni won gbe e si pada si Nigeria nibi.
”Gege bi ipo mi
lorile-ede yii, awon eri kan wa daadaa ti mo ni, eyi to fihan wi pe awon omo
kekeeke metaleIogun kan ti wa, to je
pe nise ni won n se bii Bobrisky,
eyi bani ninu je pupo, bee la setan lati fopin siru awon iwa odaran yii.”
Bobrisky |
Bi
Otunba Olusegun Runsewe ti soro yii tan ni Bobrisky naa da a lohun, ohun to si
so ree; “Mo gbo pe enikan to wa
ninu ijoba n so nipa mi, e ba mi so fun un daadaa wi pe mo n duro de o, o maa
too ye e wi pe, awon to ju u lo daadaa ni mo maa n ba se lagbo ijoba. Ki i se
iru oun yen, o kere. O jo pe eni yen gan-an ko mo ohun to ku mo, pelu gbogbo
ohun to n sele ni Nigeria yii, oro emi Bobrisky lo wa ku fun un lati te lewo
bii igba, ko si wahala o, mo tun fi n loruko si i ni.”
Te o ba gbagbe, lana-an ode yii ni Bobrisky di eni
odun mejidinlogbon, ariwo to si n pa ni pe, ana Satide ojo Abameta yen, ilu Eko
maa mi titi, nise loun yoo fi ayeye nla ti oun fe se mi Eko titi.
Bo tile je pe ileri nla ti Bobrisky se niyen o,
sugbon nise lawon olopaa ya lu ibi to ti fe se inawo e, ti won si le kaluku
danu, bee ni won loun paapaa fese fe e.
Lojuese ti isele ohun ti waye lawon eeyan e ti so
pe nise lokunrin naa fenu ko, won ni Otunba Runsewe ti o gbe enu e ni igbekugbe
si yen gan-an lo jewo ara e han an. Bee la gbo pe, pelu igbese yii, o see se ki
opin deba gbogbo iwa ti okunrin to n se bii obinrin yii n hu kaakiri ilu.
Bobrisky |
Agbenuso fun ileese olopaa, Bala Elkana, ti soro
o, alaye to si se nipa bi won se gbe ibi ayeye Bobrisky tipa ni pe, olobo kan
lo ta awon wi pe, o see se ki wahala be sile nibi ti won ti fe se ayeye ohun,
ati pe ileese olopaa ko nivi faaye gba ohunkohun to le koba alaafia ilu.
Ile igbafe kan ti won n
pe ni Pearls Gardens ni Lekki Phase 1 ni iba ti waye lana-an, nigba ti omi-in
iba tun waye ni Paradise Boat Club, ni Victoria Island loni-in.
0 Comments