GBAJUMO

SAKA Ọ̀RỌ̀BỌ̀ ṢÈDÁRÒ ỌBA ONÍRÙ TÓ KÚ * Ó NÍ, AKỌNI ŃLÁ LÓ LỌ NÍ NIGERIA


Oba Oniru
Aare egbe àwọn olorin fuji nígbà kan, Alhaji Saka Ayinde Odunsi ẹni tàwọn èèyàn tún mo sì Saka Orobo tí ṣàpèjúwe Ọba Oniru, Alayeluwa Oba Idowu Abiodun gege bí òpó ńlá kán to wo nílé Yoruba lójijì, táwọn èèyàn kò ní í gbàgbé láéláé.
Orobo nínú ọ̀rọ̀ ẹ sọ pé, títí láyé ni iran Yoruba ati Nigeria lapapo yóò máa rántí ipa manigbagbe tí Ọba Oniru kò laarin ọmọ adarihunrun
Ó fi kún un pé ilosiwaju rere ti Kabiyesi náà mú bá ìlú e, Eti-Osa, ipinle Eko lapapo kò ṣe fowo ro seyin rárá, bẹ́ẹ̀ ni àjọṣepo to dán moran to ni pẹ̀lú àwọn ọba alayé akẹgbẹ́ e ko sai mú eto àlàáfíà to dara wá ní gbogbo àgbègbè ẹ àtàwọn íbi tó sún mọ́ ọn.
Lára àwọn ohun iwuri tí Kabiyesi yìí ṣe nígbà ayé ẹ ní eto ilé kiko lọ́nà ìgbàlódé sì Oniru estate ni Victoria Island, l"Ekoo èyí tó mú ìlú e rẹwà gidi, tó sì sọ ó di apewaawo lágbègbè ohun."
Saka Orobo, olorin fuji
Orobo nínú ọ̀rọ̀ ẹ sọ pé "Mo ń fi asiko yii sedaro pelu awon molebi Ọba Óniru, àwọn aráàlú lori ikú Oba wá, Alayeluwa Oba Idowu Abiodun Oniru. Ikaya ńlá ni ikú ohun je sugbon a dúpẹ́ wí pé isẹmi tó dara ni wọn lo, bẹẹ ni wọn fi igbe ayé wọn ṣe òpòlopò èèyàn looore kí Olúwa bá wa ké wọn, kò fi wọn sì àlùjonna onidera.
“Nígbà ayé wọn, bàbà dáadáa ní wón, tí ilé àti ona wọn gba gbogbo èèyàn, ìdùnnú àti àlàáfíà ni Ọba Idowu Abiodun Oniru máa ń wà fún gbogbo ènìyàn, èyí tó mú un yàtò púpò, tí àwọn èèyàn sì máa ń rí í gege bíi bába gbogbo ìlú "
Odun 1937, ní wón bí Oba Idowu Abiodun Oniru, ọjọ́ Aje Monde ose yìí ni Kabiyesi ohun jáde láyé léni ọdún mejilelogorin.


Post a Comment

0 Comments