GBAJUMO

SHEIK MUYIDEEN, JAGUNMOLU BARIGA, OGA BELLO, OGOGO ATI GBOGBO OLORIN ISLAM YOO PEJU *BI OKIKI-OMOTAYEBI SE FE DANA ARIYA NLA

“Loju baba mi, oniranu ponbele ati onisekuse lenikeni to ba ti gbe igba orin, paapaa ti tohun ba je obinrin, sugbon oro ko ri bi won se ro o mo, nitori lojoojumo ni won n dupe wi pe awon ti n jeun omo bayii.”
Eyi ni ohun ti okan pataki lara awon olorin esin Islam to n se daadaa lasiko yii so, nigba to n ba akoroyin wa soro.
Hajia Shukurat Balogun Oluwakemi loruko e, sugbon bii aso onisuga lo se gbajumo laarin awon olorin, tawon eeyan si tun maa n pe e ni Okiki-Omotayebi.
Ki i se orin nikan ni won mo on mo, ojulowo alaga ijokoo ati alaga iduro tun ni paapaa, iyen awon to maa n dari eto nibi ayeye idana igbeyawo.
Ninu oro e lo ti so pe, “Ni nnkan bi odun meedogun seyin ni mo bere si korin jeun, sugbon lati kekere ni mo ti feran orin. Awon orin ibile gan-an la maa n ko nigba yen ni adugbo Bariga l’Ekoo ti won bi mi si, nigba ti mo wole kewu ni mo deni to n korin Islam nitori ohun mi to dun, bi mo se di asaaju olorin niyen nile kewu wa, iyen Darul-Rahmat-wal-Irshaat ni Bariga l’Ekoo.”
Okiki-Omotayebi fi kun oro e wi pe, “Gbogbo ilakaka mi lati korin lawon obi mi ko fowo si rara, won ri awon olorin gege bi oniranu, ti ko fe ise gidi se, paapaa obinrin. Ni gbogbo igba ti mo koko bere, ti mo ba so pe mo n ba afaa mi jade; a ni ode ere, inu won ki i dun si i, sugbon nigba to ya, ti ise orin yii ti n gberegejige mo mi lowo, ti awon eeyan ti n mu iroyin lo ba awon obi mi nile, wi pe omo yin lo korin nibi ta a lo loni-in, to si se daadaa, nibi tawon obi mi ti n yi okan pada niyen, bee lemi naa pada deni amuyanga fun won.”
Nigba to n so nipa eni to fi se awokose laarin awon olorin, Hajia Shukurat so pe, “Alaaja Aminat Babalola eni tawon eeyan tun mo si Omotayebi ni awokose mi nidii ise orin. O ni iye odun ti mo lo pelu won ki emi naa too da duro, Alhaji Kamorudeen Ayeloyun gan an lo fa mi le won lowo, idi niyen tawon eeyan mejeeji yii fi se pataki lowo mi pupo.”
Odun 2009 lo so pe, oun so orin kiko di ise, nigba to si di odun
2010, nigba yen gan an lo gbe rekoodu akoko e jade to pe akole e ni Oba To Rewa, odun 2013 lo semi-in to pe ni Iwa Rere, bakan naa lodun 2016 lo se rekoodu alasepo pelu awon oje nla nidii ise orin bii Alhaji Kamorudeen Ayeloyun, Alhaja Aminat Omotayebi, Ahaji Ridwan Dosunmu, Alhaja Mistura Aderounmu ati Hajia Jejeniwa Kifayat, ti won si pe akole orin ohun ni Ko ye mi.
Rekoodu kerin lo fe gbe jade bayii, ati pe ayeye nla lo fe fi ifilole e se.
Alaye to se lori inawo ohun niyi, “Gbogbo eto lo ti pari bayii lori ayeye onibeji ohun, mo fe se ikojade rekoodu mi tuntun, bee ni mo fe fun awon ti won ti n satileyin fun mi lojo pipe, ni ami eye nla.
Lara awon eeyan ti a n reti lojo naa ni, Oga Bello, Alhaji Adebayo Salami, Alhaji Taiwo Hassan Ogogo, Jagunmolu ile Bariga, Oba Badrudeen Timson, Alhaja Aminat Omotayebi, Ibrahim Itele, Arike Gold ati gbogbo olorin esin Islam pata. Gbajumo osere tiata nni,  Jide Awobona ati Lateef ni yoo dari eto ohun.
Nibi ayeye yii, Oniwaasi agbaye nni, Sheik Muyideen Ajani Bello ni yoo se waasi ni.

Post a Comment

0 Comments