Lati fi sami ayeye ogota
odun ti gbajumo osere tiata nni, Alhaja Hassanat Yetunde Akinwande, eni tawon
eeyan tun mo si Yetunde Wunmi pe loke eepe, pereu leto ti bere lolokan-o-jokan
bayii.
Lara awon eto ti obinrin
yii fe fi sami eye ojoobi nla naa ni sinima tuntun kan, eyi to fe fi so itan
igbesi aye ara e lati fi ko awon eeyan lekoo, paapaa awon ewe to n bo leyin.
Ninu alaye ti osere-binrin
yii se fun wa lo ti fidi e mule wi pe, ayeye naa maa larinrin, ati pe idupe nla
loun fe fi se pelu.
O ni, “Ope nla ni mo n du
bayii fun anfaani nla ti Olorun fun mi
lati wa laye loni-in. Se meji ni wa, ibeji ni mo wa saye o, o kan je pe eni keji
mi ti ku tipe ni, iyen latigba ta a ti wa ni kekere. Okunrin ni paapaa. Mo dupe
loni-in wi pe gbogbo ohun ti eeyan n se gege bi omoluabi ni Olorun se fun mi
nidii ise sinima ti mo yan laayo yii. Mo lokiki, mo bimo, mo tun ti ni omo omo,
mo nile lori, bee ni mo n fi moto sese rin, ti okiki mi latigba ti mo ti bere
ise sinima ko si womi. Ope ni mo da o,
ki Olorun tubo gba ope mi.”
Bee gege lo fi kun un pe,
ninu sinima yen lawon eeyan yoo ti mo asiri nla ti oun ko ba enikeni so ri, eyi
ti oun nigbagbo wi pe yoo je eko nla fawon ogo weere ati gbogbo omo eda eniyan.
Laarin awon osere tiata
Yoruba loni-in ni Nigeria, okan lara awon to gbajumo daadaa, ti awon eeyan mo
si osere to lami laaka ni Alhaja Hassant Yetunde Wunmi n se.
O fe to ogoji odun bayii ti
Yetunde Wunmi darapo mo awon to n se ere ori itage. Nibi tawon eeyan ti koko mo
on daadaa ni odo okunrin osere tiata Yoruba kan, Alagba Sunday Akinola, eni
tawon eeyan tun mo si Mogaji Feyikogbon ninu awon ere olose metala to
gbajugbaja lori telifisan kaakiri ile Yoruba nigba kan, iyen Feyikogbon.
Nigba to ya ni osere tiata
yii darapo mo Alade Aromire, lasiko igba ti sinima Yoruba gbode kan lori fidio
agbelewo, nibi ti okiki e ti bu yo niyen o, ti o si se bee di ilumooka nla ninu
awon osere tiata lobinrin.
Bi Yetunde Wunmi ti se je
osere tiata, bee naa lo ti se opo sinima pelu, ti Olorun si ke e daadaa nidii
ise naa.
Ni bayii, o ti so pe lara
awon eto ti oun fe fi sayeye ojoobi ogota odun ti oun pe lori oke eepe ni
ifilole sinima nla kan, ti yoo da lori itan igbesi aye oun. Gbongan nla TIME
SQUARE n’Ikeja l’Ekoo lo so pe ayeye ohun yoo ti waye lojo ketalelogun osu keji
odun yii.
Alhaja Salawa Abeni ni yoo
korin fun un lojo naa, nibi ti gbogbo awon olorin pata, awon osere nla nla yoo
ti pe, ti ese yoo pele paapaa lati ba okan lara won sajoyo nla.
0 Comments