Ninu atejade to fi sita lo
ti so pe, “Mo fe fi asiko yii so fun gbogbo eyin ololufe wa wi pe ayeye
OMOTAYEBI DAY ta a ti kede e wi pe yoo waye lopin ose yii ko ni i see se lasiko
yii latara ofin konile-o-gbele ti ijoba kede e. A fe fi da yin loju wi pe ni
kete ti ijoba ba ti aisan buruku yii,
CORONA VIRUS ba ti kase nile, lojuese naa la o fi asiko ti ayeye ohun yoo waye
sita.”
Sannde to n bo yii lo ti
kede tele wi pe ayeye naa yoo waye ni Time Square, n’Ikeja l’Ekoo, sugbon
wahala aisan CORONA VIRUS to gbode kan yii lo mu un fagile na, to n si reti
igba ti ijoba yoo so pe ajakale arun ohun ti kase nile.
Okan lara awon olorin esin
Islam to lami-laka daadaa ni Alhaja Aminat Babalola eni tawon eeyan tun mo si
Omotayebi. Lodoodun lo maa n sayeye
ohun, lati odun to koja naa lo ti kede wi pe, oun yoo se todun yii lona to
yato, bee lawon ololufe e kaakiri agbaye ti fokan si i pe, asiwaju awon olorin
Musulumi lobinrin yii yoo se bebe lodun yii.
Egbe kan wa ni Nigeria yii,
awon olorin Musulumi lo ni in, ISMAN loruko re n je, Omotayebi yii si ni Amira
won, eyi to tumo si Asaaju lobinrin.
0 Comments