GBAJUMO

BAALE ILU ABIJO, OLOYE HAKEEB ALARAPE ADAMS TI KU O

Kutu owuro oni ni Baale Ilu Abijo nijoba ibile Eti-Osa lagbegbe Lekki l’Ekoo jade laye.
Ninu atejade ti omo oloogbe ohun fi sowo si wa, Omooba Aarinola Adams, okan ninu awon gbajugbaja osere Yoruba lo ti so pe, eni odun mejilelogorin ni baba naa ko too dagbere faye.
Siwaju si i, a gbo pe leyin aisan ranpe ni baba naa doloogbe, iyen lowuro oni, Tosde Ojobo.
Igbese lati sin baba naa nilana esin Musulumi ti bere, eyi ti won so pe yoo waye loni-in.
Opo omo ati omo-omo lo gbeyin oloogbe yii atawon iyawo pelu.
Nigba aye e, bi baba yii ti se je Baale ilu Abijo, bee naa lo je Imaam Agba fun mosalasi ilu Langbasa nijoba ibile Eti-Osa l’Ekoo, ki Olorun te e safefe rere

Post a Comment

0 Comments