GBAJUMO

WON TI DAJO FUN FUNKE AKINDELE ATI OKO E O...IJOBA NI KI WON LO SE....


Awada ni won koko pe oro ohun, sugbon ni bayii, ijoba ti pase, bee ni won ti so pe Funke Akindele ati oko e Abdul Rasheed Bello gbodo jiya ese won, ki won si wa ni ipamo fun ojo merinla gbako.
Nile ejo Majisireeti to wa l’Ogba l’Ekoo ni Adajo Yewande Aje-Afunwa ti so pe ijiya ese gbajumo onitiata yiii ati oko e ko ju ki won sise sin ilu fun ose meji gbako, bee ni won yoo tun sanwo itanran egberun lona ogorun-un naira enikookan won (N100,000).
Gege ba a se gbo, wakati meta lojumo ni won yoo fi maa sise ohun laarin ojo Monde si Fraide. Adugbo mewaa otooto ni won si gbodo lo, nibi ti won yoo ti maa da awon eeyan lekoo pataki bi won se gbodo maa tele ofin ijoba lojuna lati gbogun ti ajakale arun corona-virus to gbode kan. Bakan naa ni won tun so pe awon mejeeji gbodo fi ara won pamo fun ojo merinla gbako, eyi ti awon eeyan ti won ba fura si pe o see se ki won ti lugbadi aisan ohun maa n se, ki won ma ba a ko ran elomi-in.
Te o ba gbagbe, lana-an ode yii ni wahala ohun bere nigba ti gbajumo osere nla yii sayeye ojoobi fun oko e nile won ni AMEN ESTATE, lagbegbe Ibeju Lekki, l’Ekoo.
Ayeye ojoobi ni Funke Akindele se fun oko e o, nni won ba fi fidio ti won ya sori ero alatagba. Bi fidio ohun se gori afefe ni ijangbon nla ti de, ki oloju si too se e, oro ohun ti di wahala nla laarin idile Funke Akindele onitiata ati ijoba Nigeria.
Se saaju akoko yii ti ajakale arun CORONA-VIRUS ti ko wahala wolu, ti gbogbo agbaye si n wona abayo si aisan to n sa gbogbo aye laamu. Eyi gan an lo mu ijoba kede ki onile-gbele, bee gbajumo osere tiata yii naa wa lara awon ti won n pariwo lori telifisan wi pe ki kaluku tele ofin ati ilana ti ijoba gbe kale, ki awon musulumi ma lo si mosalasi lo kirun akipo mo, ki awon elesin Kristeni naa rora maa pe Jesu ni koro yara won.
Bee gege lawon onileese nla nla naa gbe ilekun tipa, ti ijoba si so pe enikeni ko gbodo maa rin kaakiri, bee ni ko gbodo si apeje tabi ijokoo olopo eeyan ni gbogbo ilekile ni Nigeria ti o ba ti ju ogun eeyan lo.
*O jo pe oju n ti Funke nibi yii ni o
Bi ofin yii se wa niyen o, sugbon nigba ti fidio ojoobi awon Funke jade, ero repete ni o, nibe yen gan-an lo ti lufin ijoba; ti won si ti so pe won yoo jiya ese won pelu owo itanran egberun lona ogorun-un naira (N100,000) pere.
Ni ti Funke Akindele, obinrin yii naa ti soro o, alaye to si se ni pe, ki i se pe oun mo on mo ko awon eeyan jo lati sayeye fi lu ofin ijoba. O ni, “Ki i se pe mo fe se alaye yii lati se awijare, bikose pe mo fe toro aforiji, bee ni mo si fe ki gbogbo aye mo pe saaju ki ijoba too kede ki onile-gbele lemi atawon iko ta a jo n ya sinima wa tuntun ti a pe ni Omo Ghetto Saga ti wa loko ere nibi. Gbogbo awa ta a jo n se sinima yii la fe to ogorun-un eeyan, bo tile je pe ninu won naa ko si pelu wa lasiko yii, sugbon awon kan wa nibi pelu wa, paapaa awon ti won ki i gbe l’Ekoo.
“Lara awon ta a lo ninu fiimu tuntun yii naa ni Naira Marley, gbajumo olorin, oun naa ti wa loko ere wa saaju ki ijoba too pase wi pe ki onile-gbele. Gbogbo awa ta a jo wa nibe ni won ti wa pelu wa ni nnkan bi osu kan, elomi-in ose, awon mi-in ojo, saaju ki wahala Corona-virus to sele. Ko si enikeni to ti ile wa ba wa sajoyo lana-an,
“Mo fe fi asiko yii toro aforiji, bee ni mo fe fi da gbogbo araye loju wi pe, a ko mo on mo se e o, asise wa ni bi a se gbe fidio yen sori ero ayelukara.  Mo fe fi da gbogbo araye loju wi pe mo duro sinsin pelu ijoba lori igbogunti ajakale arun COVID 19 to gba igboro kan yii, bee ni mo setan lati maa tele gbogbo ohun ti mo ba so, ilu Nigeria ko ni i baje o, bee ni mo toro ki Olorun ba wa wo gbogbo agbaye san. Leekan si i, mo toro aforiji o,”

Post a Comment

0 Comments