GBAJUMO

Amẹrika ni Atinukẹ n gbe, ṣugbọn lojoojumọ lo sọ pe awọn ẹlẹgbẹ imulẹ lati Nigeria n wa yọ oun lẹnu


Orilẹ-ede Amerika lọhun-un lo n gbe, agbọsọgbanu iroyin gan-an lohun to sọ pe o n ṣẹlẹ si oun. Atinukẹ Ọlanbiwọninu (Ki i ṣe orukọ ẹ gan-an niyẹn fun idi kan pataki) ti lọ sẹwọn ri, nibẹ naa ni iṣoro to n da aye ẹ laamu yii gan-an ti bẹrẹ, nibi ti awọn ẹmi airi kan ti n ba a finra, ti wọn si n da a laamu gidigidi.

Loju ọpọ eeyan bii alọ apagbe gan-an ni ọrọ ẹ a fẹ ri, ṣugbọn  Arabinrin ọlọmọ kan yii ti sọ pe, ki i ṣe arọba tabi alọ loun n sọ, ohun to n ṣẹlẹ si oun gan-an ni, bẹẹ loun nilo iranlọwọ.

Ninu alaye to ṣe fun wa lo ti fidi ẹ mulẹ pe orilẹ-ede Amẹrika ni oun n gbe, ati pe igbagbọ oun ni pe ti oun ba sọ iṣelẹ buruku to ti fẹẹ sọ ohun di nnkan mi-in yii, boya awọn ọmọ Nigeria ti wọn ba ri i ka le wa ọna abayọ si ohun to ṣẹlẹ si oun lọwọlọwọ. Bẹẹ naa lo fi kun un pe boya awọn imulẹ yooku le ba awọn eeyan ọhun sọrọ ki wọn fi inu ile oun silẹ, nibi ti wọn ti n dana buruku ya oun.  

Atinukẹ Ọlanbiwọninu (Gẹgẹ ba a ṣe sọ ki i ṣe orukọ ẹ gan an niyẹn), ọmọ Yoruba ni, ohun to ba wa sọ gan-an niyi:

“Ọmọ ilu Ṣagamu ni mi, ninu oṣu kejila ọdun 1979 gan-an ni wọn bi mi. Ileewe Mayflower Junior ati Secondary School, ni mo lọ, bakan naa ni mo kawe jade ni Kwara State Polytechnic, nipinlẹ Kwara.

“Iranlọwọ gbogbo ọmọ Nigeria gan-an ni mo n wa bayii, nitori ohun ti mo n la kọja ki i ṣe kekere. Iriri aye mi ju ọjọ ori mi lọ. Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ni wọn fogun aye ja mi lorilẹ-ede Amẹrikan nibi. Yoruba ni gbogbo wọn, bẹẹ orilẹ-ede Nigeria naa ni gbogbo wọn n gbe, ṣugbọn wọn ko le ma yọ si mi nibi.


“Ninu ẹgbẹ wọn ti mo n sọ yii, oriṣiriṣi awọn eeyan lo wa laarin wọn to je pe iṣẹ ti wọn maa n ṣe ni ki wọn pa eeyan danu. Ninu wọn naa la ti ri awọn kan to jẹ pẹ ẹmi ti wọn maa ṣe lofo ni wọn maa n wa kiri, o si ni bi wọn ṣe maa n ṣẹ. Niṣe ni wọn yoo wo kadara onitọhun, ti wọn yoo si pa a danu.

“Ti wọn ba ti ri i pe ẹni ti wọn lọ wo kadara ẹ yii ko ni oore gidi kankan lara mọ, niṣe ni wọn yoo pa a danu tabi ki wọn gbe e ju sinu ọgbun ilẹ lọhun-un. Bẹẹ ọgbun ilẹ yii ni akasọ oriṣiriṣi to wọ inu ẹ lọ. Eyi to jinna ju naa lo fẹẹ ti onka bata ẹsẹ mejilelọgọta si isalẹ nigba ti awọn mi-in jẹ iwọn bata ẹsẹ mẹrinlelọgbọn si mẹtalelogun. Ohun to ṣeni laanu ni pe ọpọ eeyan ni ko mọ aṣiri awọn eeyan buruku yii, emi mọ ọn daadaa, ohun to si fa iṣoro mi niyẹn.

“O ya ẹ gb̀ọ bi mo ti ṣe ṣalabapade wọn. Ọgba ẹwọn kan wa to n jẹ Fortbend County ni ilẹ Amẹrica, nibẹ ni mo wa ti mo bẹrẹ si ri oriṣiriṣi nnkan ti wọn n kọ sara ogiri, Nigba ti yoo si fi to bii ọjọ mẹta, iya mi ni mo bẹrẹ si ri, bẹẹ ni mo n ri awọn ara ile wa, ti mo tun n ri awọn ọrẹ mi to sun mọ gidigidi. Iyalẹnu nla ni eyi jẹ fun mi, bẹẹ lo jẹ ohun to ya mi lẹnu gan-an bi mo ṣe n ri awọn ti mo fi silẹ ni Nigeria lọdọ mi ninu ọgba ẹwọn nilẹ Amẹrika nibi.

“Ori oke kan wa ti o n jẹ Ori Oke Imẹsi, bi mo si ṣe ri i, ọkan ninu ilẹ Yoruba lo wa. Bi wọn ṣe n gbe mi kiri oke yii bẹẹ naa ni mo n rira mi lawọn ibi kan bii Iyin Ekiti. Umogbo. Akungba. Ilogbo. Aaafin Elebushi. Ayeide Ekiti, bẹẹ ni gbogbo asiko yii, ninu ọgba ẹwọn naa ni mo wa. Irin-ajo mi sọgba ẹwọn nilẹ Amẹrika, itan ọjọ mi-in niyẹn o.

“Ni bayii, oriṣiriṣi nnkan lo n ṣe mi, bi mo ṣe n ri ejo lagbari mi, bẹẹ ni gbogbo ori mi dabii ẹni pe apola igi ni. Niṣe lo da bii ẹni pe wọn n fi ẹya ara mi ṣe ipese. Bii igba ti wọn so apa kan ara mi papọ soju kan, ti ko ṣe e gbe daadaa.

“Niṣe ni oju mi maa n dudu, ti maa si maa ri gbogbo ibi ti wọn ba ti n ṣepade wọn ketekete. Bẹẹ ni apa kan ẹsẹ mi dabii igba to jẹ pe ike ni wọn fi ṣe e. Aimọye igba lo maa n dabii ẹni pe gbogbo ara mi ti di ejo.

“Bo ṣe n ṣẹlẹ si mi yii, bẹẹ naa lo n ṣe ọmọ mi ti ko ju ọmọ ọdun mẹsan-an lọ. Oriṣiriṣi orukọ awọn awo lo maa n dun lagbari mi, awọn ọrọ bii Etutu ilegba, ilepa aye ati ọrun, ọyẹku. Kudigba, Ogbe idena, Ejiogbe, Edidi, Ilodi, Ayẹta, Ayeti. Ogbo  ati bẹe bẹẹ lọ. Bẹẹ ni mi o mọ ohun ti awọn ọrọ yii jẹ.

“Bii ẹni pe ẹsẹ mi kan ju ara wọn lọ ni, bakan naa ni ̀ọwọ mi ṣe ri. Awọn nnkan bii aran ati ẹyẹ kan ti wọn n pe ni owiwi pẹlu adan ni mo maa n ri ninu agbari mi. Bakan naa ni wọn tun ni iyẹpẹ kan, to dabii alawọ wura ti wọn gbe si mi nikun, eyi si maa n jẹ ki inu mi ṣe bii gba to kun, ti mo ba so bayii, oorun yẹn ki i daa rara.

“Gbogbo ara mi pata lo dabii igba ti wọn fi abẹrẹ gun, bi mo ṣe n ri eku to n rin kiri naa ni mo n ri ijapa ati ejo, bo si ṣe wa niyẹn fun ọjọ mọkanlelogun. Bẹẹ ni wọn ṣe e fun ọmọ mi naa. Ni gbogbo ẹyin mi bayii, bii ẹni pe oriṣiriṣi nnkan ti wọn fi n jagun ni wọn ko sibẹ.

“Ọmu igbaaya mi mejeeji, bii ẹni pe igbin ati ẹyẹ lo wa nibẹ ni. Niṣe ni wọn lawọn yoo pa ọmọ kanṣoṣo ti mo bi. Gbogbo ibi ti mo ba lọ pata ni wọn n ri. Bii ejo bayii ni ahọn ẹnu mi maa n ri, ti ẹsẹ mi paapaa a si maa jọ bii ejo.


“Gbogbo igba ni mo maa n ri wọn ninu yara mi, awọn imulẹ yii ko fi mi lọrun silẹ rara, koda nile mi gan an ni wọn ti n ṣepade lalaalẹ. Nibi ti wọn n ṣọ mi kiri de, wọn ko jẹ ki n ri alaanu rara. Mi o le sun daadaa mọ, gbogbo ayẹwo ti wọn ṣe fun mi pata lawọn dokita oyinbo ko ri nnkan to n ṣe mi. Ohun ti mo mọ ni pe awọn alagbara aye kan ni wọn ba mi fa a, bẹẹ mo ni iya laye, ko si si ninu akọsilẹ pe baba mi ṣe awo tabi imulẹ kankan pẹlu ẹgbẹ awo tabi imulẹ kan bayii. Awọn ohun ti mo si n ri kọja oye mi o.

“Ohun to tun ya mi lẹnu ni bi ọmọ mi ti ko ti i ju ọmọ ̀ọdun mẹsan-an lọ ṣe bẹrẹ si ni ṣe nnkan oṣu-obinrin lojiji, bẹẹ ni ẹjẹ n ya lara ẹ lọna to jọ mi loju gidi.

“O ni nnkan kan ti wọn n ṣe fun mi ninu agọ ara mi to n jẹ ki ara maa ta mi nigba gbogbo bii ẹni ti wọn da ata si lara. Oorun ki i kun mi mọ, bẹẹ ni mi o ni ifọkanbalẹ kankan, Ọlọrun nikan lo le gba mi lọwọ awọn ti wọn n gbe inu okunkun ta ọfa sinu aye mi yii. Iriri mi ree o, niṣe lawọn alagbara aye kan ti sọ ile mi di ibugbe wọn, ti wọn fẹẹ da igbesi aye emi ati ọmọ mi ru, koda nibiiṣẹ mi paapaa, gbese nla ni wọn n ko mi si. Ẹ gba mi o, ẹyin abiyamọ aye.

“Mo ri i pe o ṣe pataki ki n ke gbajare faye boya mo le rẹni to maa gba mi. Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan le maa ro pe ori mi ti daru, tabi boya mi o mọ nnkan ti mo n ṣe, eleyii ko ri bẹẹ rara, awọn alagbara aye kan ni wọn n da mi laamu, ti wọn sọ agọ ara mi di aaye ibi ti wọn n ko oriṣiriiiṣi nnkan si. Iranlọwọ ẹyin eeyan ni mo n fẹ fun ọmọ mi ati fun ara mi paapaa.”

Lati fidi ọrọ Aranbinrin yii mulẹ, eyi gan-an lo mu wa kan si awọn eeyan ẹ ti wọn wa ni Nigeria nibi, alaye ti wọn si ṣe ni pe loootọ lawọn mọ pe idaamu n ba obinrin yii. Mama to bi i tiẹ sọ pe oun ko dakẹ, gbogbo ọna ti yoo gba bọ ninu wahala naa loun n ba kiri.


Bakan naa ni iya ẹ fi kun un pe ko si ẹni to n ṣe awo ninu iran oun tabi baba ẹ, oun ko si mọ bi ọrọ ẹ ṣe ri bo ti ṣe ri yii, nitori oun paapaa ki i ṣe awo tabi ni imulẹ pẹlu enikẹni.

Aburo arabinrin yii ti oun naa ba wa sọrọ sọ pe ṣaaju ki o too lọ sẹwọn ni nnkan dan mọran daadaa fun un, to si maa n ran awọn eeyan sile daadaa, ṣugbọn latigba to ti de ni nnkan ti daru, ti ẹgbọn oun ti sọ pe awọn kan wa ti wọn fẹẹ ba oun laye jẹ.

Post a Comment

0 Comments