GBAJUMO

Idibo 2023: Awọn aṣofin Eko rọ araalu lati gba kaadi idibo

Faith Adebọla, Eko
Kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Eko lawọn aṣofin ipinlẹ naa ti ṣepade apero pataki kan l’Ọjọbọ, Tọsidee, Ọgbọnjọ, oṣu Kẹfa ọdun yii, eyi to da lori anfaani gbigba kaadi idibo alalopẹ (Permanent Voters’ Card).

Apero ọhun, to waye ni gbogbo agbegbe idibo ogoji ti awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin Eko pin si, ni wọn ti sọrọ lọkan-o-jọkan lori ewu to wa ninu bawọn araalu kan ṣe dagunla si kaadi idibo naa, ti wọn ko forukọ silẹ, awọn mi-in si forukọ silẹ ṣugbọn wọn ko tii lọ gba kaadi wọn.

Ninu apilẹkọ kan ti wọn tẹ jade, eyi tawọn aṣofin naa ka nibi apero naa, wọn ni ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent Electoral Commission (INEC) sọ laipẹ yii pe nnkan bii miliọnu ogun (20 million) kaadi yii lawọn ti tẹ jade, ṣugbọn to ni in ko tii waa lati gba a, ati pe miliọnu kan kaadi naa lo wa nipinlẹ Eko, ti wọn ko tii gba a.

Ọnarebu Adedamọla Richard Kasunmu, to n ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Ikẹja keji sọ pe lilọ toun n lọ sile aṣofin naa lẹẹkẹta yii, niṣe loun n lọọ gba gbogbo ẹtọ ati anfaani awọn eeyan oun fun wọn, oun si ‘maa ja a gba ni’.

Nigba to n sọrọ ni gbọngan apero to wa ninu ọgba ileeṣẹ Lagos Television, n’Ikẹja, o ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti ṣe ọpọ eeyan loore, titi kan oun alara, oun si lẹni to le tun orileede yii to, ti yoo si mu igba ọtun de bawọn araalu, tori naa, ki kaluku tete lọọ gba kaadi PVC wọn, ki wọn si fi rọ ibo wọle fun ẹgbẹ oṣelu APC.

Kasunmu, to n darin loriṣiiriṣii lati ṣe koriya fawọn eeyan naa, sọ pe ọjọ-ọla Naijiria ṣi maa dara, ti awọn araalu ba yan aṣaaju rere sipo, bẹẹ lo sọ pe oun maa ṣoju awọn eeyan oun pẹlu akanṣe isapa toun ba jawe olubori ninu eto idibo to n bọ.

Aṣofin naa dunnu si bawọn eeyan ṣe tu yaaya jade lati pese si apero naa, wọn si dupẹ gidigidi lọwọ awọn ọba alaye ati awọn agbagba ẹgbẹ pẹlu awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lọkan-o-jọkan to pesẹ sibi apero ọhun.

Post a Comment

0 Comments