GBAJUMO

Ẹṣẹ to ni ijiya nla niwaju Allah lawọn to n dagunla lasiko idibo n da – Aafaa Sododo


Olukọ ẹsin Islam kan, Sheikh Al-Imam Abdulateef, tawọn eeyan mọ si Sododo ti ṣalaye pe bawọn eeyan kan ṣe fẹran lati maa dagunla si eto idibo, bii bi wọn ma lọọ forukọ silẹ, tabi ki wọn ma lọọ gba kaadi idibo lasiko to yẹ, titi kan kikọ tawọn mi-in n kọ lati jade dibo ki i ṣe nnkan ire rara, o ni ẹṣẹ gidi niru awọn eeyan bẹẹ n da niwaju Oluwa, afi ki wọn tọrọ aforijin ẹṣẹ, ki wọn si ronu piwada ni wọn fi le ri alujanna wọ nigbẹyin. 

Ọrọ yii jẹ yọ ninu waasi akanṣe kan ti Imaamu agba naa ṣe lasiko waasi asiko aawẹ Ramadan, akọkọ iru rẹ, ti ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party, ZLP ṣeto rẹ, ni olu-ile ẹgbẹ wọn to wa niluu Igando, nijọba ibilẹ onidagbasoke Iba, ipinlẹ Eko, lati tubọ ta awọn araalu ji lori ibaṣepọ to wa laarin ẹsin ati oṣelu, bi wọn ṣe wọnu ara wọn, ati ojuṣe ijọba, ojuṣe araalu ati tawọn aṣaaju ẹsin. 

Oniwaasi to gboye dokita ninu imọ ẹsin Islam lati fasiti Eko, LASU, naa sọ pe kedere lo foju han ninu iwe mimọ ẹsin Islam, iyẹn Kuraani pe kawọn olujọsin kopa ninu eto oṣelu, wọn ko si gbọdọ dẹyẹ si igbokegbodo iṣejọba ilu koowa wọn. O ni ọrọ ẹsin ati oṣelu lẹ papọ ni, ko si ṣee ya sọtọ, mejeeji jọ n rin ni.

Bakan naa lo tẹnu mọ ọn pe yiyan olori to daa sipo nikan lo le mu ki ilu dara. “Ẹ jẹ ka kopa ninu oṣelu, ẹ jẹ ka kopa ninu eto idibo, a gbọdọ fọwọsọwọpọ, ka lọwọ ninu yiyan awọn adari wa, ojuṣe to pọn dandan ni, tori ta o ba ṣe e, gbogbo wa la maa jiya rẹ, ohun to tun waa buru ju nibẹ ni pe ijiya nla wa fawọn to ba kẹyin si ojuṣe yii lọdọ Ọlọrun Ọba lọjọ ikẹyin, tori ẹṣẹ nla ni”. Bẹẹ lo fa ọrọ Kuraani ori kẹta ẹsẹ ikẹtalelọgọrun-un kin ọrọ rẹ lẹyin. 

O tun ni, “ofin Ọlọrun Ọba ninu Kuraani ni, niwọn igba teeyan ba ti n gbe ninu ilu kan, Ọlọrun pa a laṣẹ pe ki tọhun kopa ninu iyansipo awọn olori ati adari ibẹ, fun idagbasoke ilu naa.”

Olukọ ẹsin naa tun ṣalaye ojuṣe ijọba si awọn oludibo ati araalu, bẹẹ lo ṣalaye ojuṣe awọn araalu si awọn olori wọn gbogbo. 

Alaga ẹgbẹ ati Oludije funpo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia Labour Party to ṣagbatẹru eto waasi ọhun, Ọgbẹni Adekunle Adenipebi, to ba Alaroye sọrọ lẹyin naa sọ pe lajori idi tawọn fi ṣagbekalẹ waasi yii jẹ lati ta awọn araalu ji, paapaa lasiko aawẹ yii, ki wọn le tubọ gbaradi lati ṣe ojuṣe wọn, ki wọn si kopa ninu eto iṣelu bo ṣe yẹ. O ni eyi ni akọkọ iru eto naa ti yoo waye labẹ ẹgbẹ ZLP, o si ṣeleri pe ọpọ itaniji, ilanilọyẹ bii eyi ni yoo maa waye si i. 

O fi imọ riri han sawọn alatilẹyin rẹ, bakan naa lo sọ pe ọjọ-ọla rere wa fun Naijiria tawọn araalu ba ṣetan lati lo agbara wọn lọna to tọ lasiko idibo. 

CAPTION

Post a Comment

0 Comments