GBAJUMO

Awon oyinbo gbosuba nla fun Aralola - Ni gbogbo won ba n pariwo pe Idan gangan ree o


Ti won ba so pe idan gangan, ko selomi-in ti won n so to ju asaaju awon obinrin onilu, Arabinrin Serifat Olamuyiwa ti gbogbo aye mo si Aralola lo. Idi ni pe arewa obinrin naa ti fi Ilu ati orin dara laarin awon oyinbo alawo funfun.

 Se lawon oyinbo ati dudu la enu sile ti won ko le pa a de, nigba ti won ri ara nla ti Aralola filu da lara, ni gbogbo won ba n pariwo pe idan gangan ree o, won lawon ko ri iru idan ti Ara pa yii latojo tawon ti daye.



Gege bi a se gbo, orileede Spain lohun-un ni Aralola ti gboruko orileede yii ga, ti obinrin naa je kawon dudu ati oyinbo mo pe Olorun jogun ebun nla fun Iran Yoruba. Lara awon ayeye ti won se ni Spain ti Aralola ti dabira ni: Fuertventuraenmusica festival, Etnosur festival 

Imaginafunk festival 

Folkdelmundo festival 

CanariasJazz festival 

Canariasjazz festival 

Sinsal festival atawon mi-in

Awon ilu ti Aralola ti fakoyo ni:Fuertventura, Grand Canaria, Jean, Algaceria, Granada.



Nitori itu meje di ode n pa ninu igbo ti Aralola pa yii, lawon eeyan kan fi so pe ebun ti awon eeyan wa ni Naijiria ko mo iyi e ni awon oyinbo gbe osuba rabande fun yii, won ni iyi ati aponle ti ko si fun ebun wa la a se padanu ebun nla bii Sade Adu ati Asa sowo awon oyinbo.



 Ju gbogbo e lo, awon oyinbo ti so pe Aralola lo ye ki won maa pe ni Idan gangan.



Post a Comment

0 Comments