GBAJUMO

Ohun tí Bola Tinubu gbọdọ ṣe rèé ki ara lè tu ọmọ Naijiria - Ajadi Oguntoyinbo


Bi awon omo orile-ede yii se n pariwo lojoojumo latari inira ninla ti won n ri ninu ijoba Bola Tinubu, okunrin oloselu, to dije dupo gomina ninu eto idibo to koja yii, Ambasadọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, ti so pe afi Aare o tete gbe igbese to nipon ki ara le de teru-tomo, bee lo so pe, oun setan lati ba a tuko eto isakoso lawon ibi to ba ye, ti won ba le nawo kajo-see soun naa ninu ijoba tuntun yii.  

Okunrin gbajumọ onisowo, to tun jẹ oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP, nipinlẹ Ogun, sọ pe bi nnkan ṣe n lọ yii, afi ki Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ta kiji lori oro epo, atawon ibi ti awon omo orile-ede yii ti n koju isoro to lagbara, ki kinni ohun too bowo sori.

Oguntoyinbo so awon oro yii lasiko to gba ẹgbẹ awon oniroyin lede Yoruba, iyẹn, ‘League of Yoruba Media Practitioners’ lalejo lọfiiṣi ẹ, lọsẹ to kọja. Nibe naa lo ti sọ pe oun jẹ ẹnikan to fẹran lati maa wa nibi ti wọn ba ti n ṣe ohun to le mu aye araalu dara, ati pe afojusun oun ni lati fowosowopo pelu ijoba yii lati wa ojuutu sawon ibi to ti ku die kaato, eyi to le fopin si ariwo ise, osi ohun iya tawon omo orile-ede yii n pariwo e kikankikan lasiko yii. 

Oguntoyinbo to tun jẹ akọroyin, eni ti tun n se alakooso ileeṣẹ 'Bullion Go-Neat Global Ltd’, nibi ti won ti n pon ohun mimu amarale fawọn ọkunrin, iyẹn ’Coco-Samba’, tun sọ pe, o ṣe pataki ki ijọba Bola Tinubu fi kun owo oṣu awọn oṣiṣẹ latari bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori lasiko yii.

O ni, "Ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) ko pọju gẹgẹ bi owo oṣu to kere ju fun awon oṣiṣẹ, nitori nigba ti wọn ti fowo kun owo epo ni gbogbo nnkan ti gbowo lori, ti inira si ti pọju fawọn araalu.’’

Bakan naa lo fi kun un pe, nise lo yẹ ki wọn mojuto ipese ina mọnamọna, ki ileeṣẹ apinnaka pọ bii ti ẹlẹrọ ibara- ẹni-sọrọ, ki wọn jẹ ki ifigagbaga wa laarin wọn, o ni nipa bayii, ni awọn araalu yoo le fi edo lori orooro lori oro ina elentiriiki, ti igbe-aye-gbadun awon eeyan orile-ede yii yoo le ni itumo gidi.

Siwaju si i, okunrin onisowo yii ko sai soro nipa iriri e nidii oselu, paapaa lori bo ti se fidi remi lasiko eto idibo to koja. Ninu oro e lo ti so pe, ko si nnkan to fa a bi ki ṣe ẹni toun fi ọkan tan, toun gbẹkẹle lai mọ pe tohun gan an ni yoo  ta oun fawọn ọjẹlu, iyẹn alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Sunday Ọlapọsi Ọginni.

O ni, 'Ko sohun to jẹ ki n ri ijakulẹ ninu idibo to kọja yẹn ju pe mo fi ọkan tan eeyan lọ, lotito lawọn eeyan pe mi si akiyesi pe ki n ṣọra fun alaga ẹgbẹ ti mo ti jade fun ipo gomina nipinlẹ Ogun, iyẹn, Sunday Ọlapọsi Ọginni, emi ni mi o gbọ. Igbagbo mi si ni pe, ko sẹni to le ta mi bi mo ṣe jẹ ọdọ yii, paapaa bo ti se je pe inu mimo ati okan rere ni mo fe fi se ohun ti mo ni fun araalu. Mo fe fopin si ise ohun iya to n je araalu ni, fun idi eyi, mi o lero wi pe enikan le di mi lowo, tabi ba erongba rere yii je mo mi lowo."

Oguntoyinbo fi kun un pe, "O ku ọsẹ kan ki ibo waye ni Ọlapọsi Ọginni lọ darapọ mọ PDP, to ta mi, to tun gbowo ori mi. Nise lo lo so fun won ninu egbe PDP pe a o dije mọ o, a ti darapọ mọ wọn."

O ni, o loun toun fẹ dije ko mọ nnkankan o, nise loun atawon eeyan oun kan ri fidio nigboro, nibi ti alaga tele ohun ti lọ ba awọn Ladi Adebutu ṣepade, to n pariwo PDP lai ba oun sọ nnkankan tele.

O fi kun ọrọ ẹ bayii pe ‘’Titi to fi ku ọtunla ta a maa dibo lo fi tan mi. Mo kabaamọ pe mo mọ ẹni to n jẹ Ọlapọsi Ọginni. Ẹyin ọdọ tẹ ẹ ba gbọ orukọ rẹ, ẹ ma duro o, ẹ sa lọ ni. Mo gbe igbesẹ lati fi to ẹgbẹ wa lapapọ leti, wọn si pe e lẹẹmẹta, ṣugbọn ko yọju si wọn, ohun ti wọn ṣe yọ ọ lẹgbẹ niyẹn.’

Bee lo tun te siwaju pe pẹlu nnkan ti Ọginni foju oun ri yii, eyi ko ni ki oṣelu yọ lẹmi oun o, ati pe ipo aarẹ lo ku toun yoo dije fun bayii, iyẹn lọdun 2027.

O ni, 'Oluwa lo ba mi sọrọ pe ki n dije fun ipo naa, labẹ asia ẹgbẹ NNPP yii naa si ni maa ti jade ni 2027. Ki i ṣe fun ifẹ ara mi, bi ko ṣe fun awọn ọmọ Naijiria ti mo gbagbọ pe wọn gbọdọ kuro ninu iṣẹ ati oṣi.

Bakan naa lo fi kun un pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ ti yoo yi nnkan pada fun NNPP, nitori nilẹ Hausa, ẹgbẹ awọn rọwọ mu, ṣugbọn nilẹ Yoruba, owo lọwọ ẹyin nilẹ ni wọn fi oro ibo yen ṣe. Bee lo so pe, iṣẹ ti n lọ lati jẹ ki wọn mọ pe a ko le maa tọ oju ọna kan naa lọ lai dan ibo mi-in wo, ati pe bi asiko ba si to, o da oun loju pe didun lọsan yoo so.

Post a Comment

0 Comments