GBAJUMO

EGBE OMO YORUBA NILUU ITALY YOO GBALEJO OONI ILE-IFE

Gbogbo eto ti pari lati gbalejo Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi lorile-ede Italy ni Satide, ojo Abameta to n bo yii, iyen ojo kokanlelogun osu keje odun yii niluu Padova nibi ayeye odun keedogun ti won da egbe naa sile.

Egbe Omo Yoruba ilu Padova je okan lara awon egbe ti won n se igbelaruge asa, ede ati ise iran Yoruba lorile-ede Italy lati maa ran awon omo Oduduwa ti won wa leyin odi leti pe ile labo isinmi oko.

Olorin pataki ti yoo fi ilu ati orin da awon alejo laraya ni ilu-mo-on-ka onifuji nni, Abass Akande Obesere tawon eeyan tun mo si Omorapala.

Ninu atejade ti aare egbe naa, Ogbeni Lanre Badmus fi sita, o salaye pe kaakiri ile
Europe ati Amerika ni won ti n reti awon alejo nibi ayeye naa, nigba ti awon omo bibi ile Yoruba kaakiri agbaye ti won tun fiwe pe naa si ti seleri lati waa ye egbe omo Yoruba niluu Padova si ki won si fi atileyin won han si ise takun-takun ti won n se fun igbelaruge asa ati ede Yoruba nile Europe.

Gbajumo soro-soro lori redio ipinle Eko, Mate Abayomi Abiodun tawon ololufe e mo si Ifa-n-kaleluya nireti wa pe yoo se atokun eto naa ti yoo bere laago merin irole.

Post a Comment

1 Comments

  1. Aku ipalemo,abawa l'aiye ati l'aye idera .Allahumo amin

    ReplyDelete