GBAJUMO

KAYODE FAYEMI DOJUTI FAYOSE L’EKITI

...LO BA SO ILE YORUBA DI TI EGBE OSELU APC NIKAN SOSO

Lati fi idunnu re han si aseyori nla ti egbe oselu APC se l’Ekiti, Aare Muhammed Buhari ti ki Dokita Kayode Fayemi ku oriire, bakan naa lo so pe, aseyori yii fi han wi pe ti egbe oselu APC lawon eeyan Ekiti n se.
Kayode Feyemi atawon molebi e tun pada sile ijoba l'Ekiti
Aare Muhammed Buhari ti wa ro awon ti Fayemi fidi won janle ninu ibo naa lati gba a bii kadara ki won si fowosowopo pelu eni to jawe olubori lati le mu idagbasoke ba ipinle ohun.
Ni kutu aaro Sannde oni, kaakiri ipinle Ekiti lawon omo egbe oselu APC ti Dokita Kayode Fayemi dije loruko e ti n yo, ti won n jo kiri bayii lori bi okunrin oloselu to ti se gomina nipinle naa tele se tun pada wole leekan si i.
Bi okunrin oloselu yii se jawe olubori ninu idije ti egbe oselu to le ni ogbon ti kopa ninu e yii se wole lawon eeyan ti n so pe, opin ti de ba egbe oselu PDP nile Yoruba. Bakan naa lawon eeyan tun fi kun un pe, aseyori yii ko ni sai mu esi rere wa fun egbe naa ninu ibo to n bo lodun 2019.
Aare Buhari fidunnu ki i ku oriire
Laaaro kutu ana Satide, ojo Abameta lawon eeyan ti n jade sita lati bere eto idibo naa. Ninu ijoba ibile merindinlogun to wa nipinle ohun, mokanla ninu e ni Kayode Fayemi ti lu egbe oselu PDP lalu-bole, ti okunrin naa si jawe olubori pelu ibo to fe to egberun lona igba (197, 459). Ojogbon Kolapo Olusola to dije loruko egbe oselu PDP lo sunmo Kayode Fayemi pekipeki ninu idije naa pelu ibo to fe to egberun lona ogosan-an (178,121).
Igbakeji Fayose ti Fayemi lu lalubole ree...
Olusola Kolapo lo n je
Saaju ki ajo INEC too kede eni to jawe olubori ninu idije ohun ni orisirisi esi ibo ti gba igboro kan. Lasiko ti eyi n waye ni ajo naa ti sare pe ipade awon oniroyin, nibi to ti fidi e mule wi pe ki awon eeyan ma se tele awon esi ibo to kun ori ero ayelujara. Nise ni INEC so pe ajo ohun nikan lo letoo lati fi esi ibo to to sita, ati pe eyi to gba igboro kan ohun, iro, ofege lasan lo po nibe.
Yato si eyi, orisirisi awuyewuye lo koko gba igboro kan lasiko ti eto idibo ohun n lo lowo, paapaa lori bi awon egbe oselu kan se n pin owo kiri. Ohun ta a gbo ni egberun marun-un naira ni egbe oselu APC n pin fawon to fe dibo, nigba ti PDP ni tie n pin egberun merin naira. Awon kan tie so pe, saaju ki eto idibo too bere rara ni egbe oselu kan ti koko san egberun meta-meta naira si akaunti awon osise l’Ekiti.
Bola Tinubu niyen lasiko to ni kawon eeyan Ekiti
fibo le egbe oselu PDP danu
Te o ba gbagbe, bo se ku bi ojo meloo kan ki ibo waye lorisirisi isele waye, ninu e naa ni igbese ti ileese olopaa gbe lati pese aabo to peye lasiko idibo ohun, olopaa to to egberun lona ogbon (30,000) nileese olopaa fi ranse si ipinle Ekiti yato sawon eso agbofinro mi-in.
Bi eto ipolongo ti se n kase nile ni iroyin kan gba igboro kan wi pe awon olopaa kolu Gomina Ayodele Fayose lasiko ti won fe se iwode ipolongo ibo. Okunrin oloselu yii so pe ilukulu ni olopaa kan lu oun, ati pe apa oun ti da, bee lorun oun paapaa ko se yin daadaa mo, ti gomina yii si n gbe bandeeji orun kiri.
Siwaju si i, o fe ma si ogunna gbongbo kan ninu egbe oselu APC ti ko de ipinle Ekiti lati polongo ibo fun Fayemi, bere latori Aare Muhammed Buhari atawon ogunna gbongbo oloselu bii Bola Tinubu, Adams Oshiomhole, Bisi Akande, awon gomina ile Yoruba atawon mi-in nile Hausa ati kaakiri Nigeria.
Fayemi ti wole pada l'Ekiti,
 kin ni yoo sele si Fayose atawon PDP?
Nise lawon omo egbe oselu APC yawo ipinle naa, ohun kan ti won si n so ni pe, awon setan lati fi igbale gba Fayose ati egbe PDP danu l’Ekiti. Bola Tinubu ni tie beere lowo awon eeyan Ekiti pe, se ko wu won ki awon naa darapo moa won ile Yoruba yooku ti ilosiwaju n ba latara isakoso egbe oselu APC nibe ni. Ebe ti okunrin asaaju oloselu to ti se gomina nipinle Eko tele si be awon eeyan Ekiti lojo naa ni pe, ki won fibo le PDP danu, ki gbogbo ile Yoruba si le je ti egbe oselu APC nikansoso.  
Ju gbogbo e lo, ninu ayo ni egbe oselu APC wa bayii pelu bi Kayode Fayemi se gba ipinle Ekiti mo egbe oselu PDP lowo. Ni bayii, gbogbo ipinle Yoruba patapata ni won je ti egbe oselu APC, ohun tawon eeyan si n so ni pe, ewe olubori ti egbe naa ja ko ni sai ni ipa pataki fun egbe oselu naa ninu ibo gbogboo-gbo to n bo lodun 2019.



Post a Comment

0 Comments