GBAJUMO

WASIU ALABI PASUMA FE SERE NLA FUN KEMI KOREDE L’E’KOO


Bi akara lawon ololufee gbajmo osere tiata nni, Alhaja Kemi atawon ololufe orin fuji, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma n ra ankara to pe ni aso ebi to fe fi sayeye ojoobi e ati ikojade sinima nla meji.

Sannde to n bo yii, iyen ojo keedogun osu yii gan-an ni pepeye yoo pon omo ni gbongan nla BALMORA lojuna Oregun, n’Ikeja l’Ekoo nibi ti obinrin osere yii ti so pe oun yoo ti dana ariya nla.

Ayeye onibeta (3 in 1) ni gbajumo osere onitiata yii to pe oruko ileese e ni Korede Films so pe oun fe se nibi ti Alhaji Wasiu Alabi Pasuma yoo ti forin da awon eeyan laraya. Sinima meji lobinrin yii fe se ikojade e, Ignorance ati Wemimo, bakan naa ni yoo sayeye ojoobi e pelu.

Yato si Alhaji Wasiu Alabi Pasuma, Oga Nla onifuji ti yoo korin lojo naa, orisirisi awon osere nla ti won loruko daadaa ni won yoo wa nibe lojo naa, bakan naa lawon gbajumo nla-nla laarin ilu ko nii sai wa nibe pelu.

Awon ti yoo dari ariya ojo naa ni Ronke Osodi Oke, Baba Tee ati MC Taofik Koyokoyo.


Post a Comment

0 Comments