Gbajumo osere tiata nni, Arinola Adams ti wa lorile-ede
Amerika bayii nibi to ti lo ya sinima e tuntun to pe akole e ni Ina Inu.
Ninu oro gbajumo osere yii lo ti so pe, “Saaju asiko yii lati
koko ya die ninu sinima ohun ni Nigeria, awon osere nla bii Madam Saje, Ogogo,
Funke Etti ati emi gan-an alara pelu awon osere mi-in ti won lami-laka la jo
kopa ninu e. Sinima ti a fi opolopo milionu ya ni, ti yoo si mi igboro titi to
ba jade.”
Nigba to n dahun si ibeere idi to fi lo pari e ni Amerika lo salaye
bayii pe, “Bi itan yen se lo, bee gege la se sagbekale e, nibi ti oro fiimu n
lo bayii, bi eeyan se n rin kaakiri orile aye, bee ni itan inu sinima naa se n ri
lasiko yii. Ti e ba wo awon sinima awon oyinbo paapaa, won le ya sinima eyo
kansoso lawon orile-ede bii marun-un tabi ju bee lo. Ile Afrika ni Nigeria nibi
ni itan Ina Inu ti bere, bee lo de
Amerika, ki o too pada wa pari ni Nigeria. Itan nla kan to yato sawon sinima ti
mo ti se tele ni, mo si nigbagbo pe awon ololufee mi yoo tubo gbadun eleyii naa
daadaa.”
Ni bayii, o ti di sinima marun-un otooto ti yoo jade latowo Aarinola
Adams. Fiimu akoko to gbe e jade lo pe akole e ni A-le-ku-lowo, leyin naa lo se
Emi Abami Eda, Aare Apase; Anu Obi ati Ina Inu to n ya lowo lorile-ede Amerika
lohun-un.
Ni nnkan bi odun meloo kan seyin lokunrin omo onile lagbegbe
Ibeju Lekki, nipinle Eko yii darapo mo awon to n se sinima Yoruba. Egbe gbajumo
osere tiata kan, Saidi Balogun lo koko darapo mo niluu Ikorodu, l’Ekoo, sugbon ko
pe nibe rara to fi te siwaju lo sodo Muyideen Oladapo eni tawon eeyan tun mo si
Lala.
Ninu akitiyan e lati tete m’oke nidii ise ohun lo tun mu un kuro
nibe lo ba okunrin kan to n je Ajani Ogunleye, eni tawon eeyan mo si Big Man
niluu Musin, l’Ekoo nibe gan-an laaye ti tete gba a, to si bere si kopa daadaa
ninu sinima tawon egbe naa n se.
O ni, “Lodo Ajani Ogunleye ni mo ti kose yege, odo e gan-an ni
mo ti se sinima A-LE-KU-LOWO, nibe gan-an ni mo ti bere, ki oloju si too se e, a
dupe pe nise la n te siwaju lojoojumo.”
Ona mi-in ti Aarinola tun ba won gba nidii ise amuludun ni orin
aladun kan ti o gbe jade ni nnkan bi odun meji seyin. Ori lo pe akole e, oun
ati gbajumo olorin Hip-hop, Q Dot kan ni won jo se e.
Yato si orin to pe akole e ni Ori yii, awon mi-in to tun ti se
ni; Ase, Papiyayin, Alufaa.
“Ni kete ti mo ba ti de lati Amerika, sinima olosoose lo wu mi
lati se bayii, ise ti pari lori e, ki a wo lokesan lati lo ya a lo ku, mo si fe
fi da awon ololufe mi loju wi pe, iru ife nla ti won ni sawon sinima bii Koto
Orun, Arelu; Eye Jomi-joke nigba kan, ti awon eeyan maa n sare lo wo o nile,
iru sinima olosoose bee ni mo fe gbe jade. Won yoo si gbadun e daadaa. Mo fe ki
awon ololufe mi maa foju sona.” Aarinola lo so bee.
Siwaju si i, bo tile je pe ise sinima lo so o dolokiki laarin
ilu, sibe Aarinola so pe, “O lohun kan to tun n mu owo wole fun mi daadaa. Ni
Nigeria ti a wa loni-in, ona kan bayii ko woja mo o, ti eeyan ba lanfaani lati
se ise orisirisi meji si meta tabi ju bee lo ki o se e daadaa, koko ibe ni pe ki
eeyan ma jale, ko si ma ba omoluabi e je. Mo maa n ra ile, mo n ba eeyan ta a,
bee ni mo mo nipa ile rira ati tita a, ohun ti a si fi n se eleyii ni lati ma
se s’ole, ko dara ki omokunrin duro soju kan.”
0 Comments