![]() |
Adams Oshimhole |
Lojoojumo ni alaga egbe oselu
APC n lo sori telifisan bayii, o si jo pe ariwo Seneto Saraki
lokunrin ohun feran lati maa pa ni gbogbo akoko to ba ti lanfaani lati ba awon oniroyin
soro.
Oro kan to si maa n tenumo ju ni
pe, ki Saraki ma safira o, nise ni ko sare gbe ipo Aare ile igbimo asofin agba
sile, nitori pe inu egbe oselu PDP to salo yen, omo egbe naa ko to nnkan nile
igbimo asofin agba, bee ni ko letoo ki omo egbe to kere ju maa se olori awon ti
won po daadaa.
Okunrin to ti figba kan je
olori awon osise ni Nigeria, to tun ti se gomina nipinle Edo fodun mejo gbako
ko too di alaga egbe oselu APC tenumo pe, “Ohun to dara fun Bukola Saraki bayii
ni pe ko kowe fipo yen sile, tabi ko pada sinu egbe APC wa, sugbon awa naa ko
le gba a mo, nitori ko si aaye e nibi. Ko yara maa sohun ni, ko si gbe ipo aare
ile igbimo asofin ju sile, nitori ipo APC ni, awa la lomo egbe to poju nibe
yen, eeyan tomo egbe e kere ko le maa soga le awon ti won lomo egbe to po ju
lo, nibo ni won ti n seru e. To ba ko
lati kuro nibe, a setan lati ba a fowo ofin to o, itiju lo maa ba kuro, iyen ti
di dandan.”
Alaga APC yii ti so pe, omo
egbe oselu APC to wa nile igbimo asofin agba je metalelaadota, eyi to fun egbe
oselu naa ni opo anfaani gege bi omo egbe to poju PDP tabi APGA lo.
![]() |
Bukola Saraki |
Sa o, okan lara awon omo ile
igbimo asofin to sunmo Saraki ti soro, iyen Seneto Dino Melaye, okunrin oloselu
omo Kogi y
ii so pe, “Isokuso ni Oshiomhole n so, ati pe ariwo lasan lo n pa kiri, bee ariwo e yii ko ran nnkankan nitori ko ni ibo eyo kan bayii to le yo Saraki nipo, o kan n so tie ni. Ade to n pariwo kiri gbe APC lo ni yii, se oye idile ni won n je nile igbimo asofin agba ni, ko si bi won se fe se e, Saraki yoo lo odun merin e pe, awon ni won ki won lo jokoo je.”
ii so pe, “Isokuso ni Oshiomhole n so, ati pe ariwo lasan lo n pa kiri, bee ariwo e yii ko ran nnkankan nitori ko ni ibo eyo kan bayii to le yo Saraki nipo, o kan n so tie ni. Ade to n pariwo kiri gbe APC lo ni yii, se oye idile ni won n je nile igbimo asofin agba ni, ko si bi won se fe se e, Saraki yoo lo odun merin e pe, awon ni won ki won lo jokoo je.”
Nigba ta a koja saarin ilu, okunrin
oloselu kan to ba Magasinni yii soro salaye bayii pe, “Ti oro ba ri bayii, o
kuku lona abayo, ohun ti Saraki le se ni pe, ko bere si ya ojule si ojule lati
fa awon omo egbe oselu APC nile igbimo asofin agba wonu PDP ki omo egbe yen le
po daadaa, ki ipo e ma ba a bo mo on lowo. Owo to maa na kuku wa, ki i se igba
akoko niyi ti awon eeyan a maa pin baagi
Ghana Must Go kiri nile igbimo asofin, to ba se e, ti nomba awon omo egbe
PDP po si i, boya ariwo ti Oshiomhole n pa kiri a je dopin.”
Ohun ti okunrin yii so ree o,
sugbon elomi-in ninu ero tie so pe, oloselu to ba tori owo tele Saraki lasiko
yii, isoro ayeraye lo maa ko ara e si, nitori egbe oselu PDP laduugbo iru eni
bee le ti ni eeyan ti enu e tole daadaa, ipadabo iru eeyan bee sile igbimo
asofin lodun 2019 le nira gidigidi, paapaa ti eni to ba dije pelu ba lagbara
daadaa.”
Ju gbogbo e, egbe APC n leri, bee ni Bukola Saraki naa ti
so pe ko seni kan bayii to le gba akata lowo akiti, nibi toro ohun yoo yori si,
oju ree iran ree.
0 Comments