GBAJUMO

AWON ARA EKO N BINU SI ILE ISE MONA-MONA *WON NI JIBITI TI WON N SE TI TO GE

Awon omo egbe Lanloodu
ati ayalegbe ree pelu asoju ijoba Eko

Lati fopin si idaamu nla ti ajo apinna-ka, iyen Power Distribution companies (DISCOS) n ko ba awon eeyan orile-ede yii, egbe awon ayalegbe ati lanloodu ti ke gbajare si ijoba ati gbogbo awon ti oro kan laarin ilu lati da si i, ki isoro ohun le wa sopin patapata. Tusde ojo kerinla osu yii ni iwode ohun waye, ilu Badia ni Ijora ti olu ile egbe naa wa lawon eeyan ti gbera, bee ni boosi nla nla bii mewaa atawon moto akero mi-in lorisirisi tele ara won, olokan-o-jokan orin ni won n ko lati fehonu won han, bee niluu Eko gan-an mi titi lojo naa.
Omooba Rilwan Zaid Ojora Akiolu ti se Aare egbe naa lo siwaju, bi awon omode se wa ninu won, bee lawon arugbo paapaa naa pelu, ohun ti okunrin ati obinrin won si n so ni pe, iya buruku ti ajo apinna-ka fi n je awon ti to ge, emi awon ko gbe e mo!
asoju ijoba ree pelu won

Ni kete ti won kuro ni Badia, ileese awon apinna-ka naa to wa ni Marina l’Ekoo ni won koko lo, leyin naa ni won ya si ofiisi won mi-in to wa ni agbegbe Alausa n’Ikeja ki won too fabo si ofiisi ijoba Eko.
Bo tile je pe ko seni kan bayii to yoju si won lofiisi awon apinna-ka ni Marina, nigba ti won de Ikeja, awon osise ileese naa gba iwe ehonu lowo won wole, ti oga kankan ko si yoju si won pelu.
Lojuese ti won ri i pe nise ni won kan da awon duro senu ona, to si jo pe won ko setan lati ba awon soro kankan lawon omo egbe ohun ti won fee to egberun marun-un wo lo si ofiisi Gomina Akinwunmi Ambode, nibe gan-an lawon osise gomina yii ti jade lati ba won soro tutu.
Omooba Ojora Akiolu lasiko to n ba awon omo egbe e soro ni Badia
Ninu alaye ti Omooba Rilwan Zaid Ojora Akiolu se lo ti so pe, “Iya buruku ni ajo apinna-ka atawon osise won fi n je wa l’Ekoo, a si mo daju pe gomina ta a ni, eletii-gbaroye ti ko ni i gba won laaye ki won maa sa pamo je wa niya. A fe ki won fopin si bi won se maa n gbe owo gegeege wa fun wa losu. Ko sina ko si owo sisan, bee la o ni i gba ki enikeni ja ina wa mo, awa ko je gbese kankan sile, ti a ba wo o daadaa, awon gan-an ni won n je wa lowo, nitori ina ti won ko fun wa, ni won n fi tipa gba owo e lowo wa. Ti ajo to n pina kiri yii ko ba ti le fun wa ni Mita, a je pe yara kan ko ni i ma san ju egbeta naira (N600) lo losu.”
Leyin ti won se gbogbo alaye yii fun awon oluranlowo fun gomina lori oro araalu, okan ninu won, iyen Ogbeni Taiwo Ayedun dupe lowo won bi iwode won ohun se je ti omoluabi, bee lo fi da won loju pe ijoba Eko setan lati da si oro ohun.

O ni, “Gege bi e se mo pe ijoba wa eletii gbaroye ni, a setan lati pe awon ajo apinna-ka ati awon asoju yin ki a le wa ojutuu si wahala ohun. Ohun to se pataki ni bi alaafia yoo se joba l’Ekoo, ti inu kaluku yoo si dun pelu.”
Lati Tusde ojo Isegun ti iwode yii ti waye kaakiri awon ibi kan nipinle Eko lariwo ti gba igboro kan, bi won ti n so o lori redio, bee lawon iwe iroyin ati telifissan naa n gbe e pelu, ohun ti awon araalu ti won si lanfaani lati da sawon eto to waye lori redi n so ni pe, nise ni ki ijoba gbe igbese to ye lori bi mita a-la-san-sile  yoo se wa kaakiri, ti awon eeyan ko ni i ma sanwo ohun ti won ko ri lo rara.
Ofiisi ajo apinna-ka n'Ikeja, Eko


Post a Comment

0 Comments