GBAJUMO

E GBA MI LOWO KEMI NELSON, IDAAMU TO N FUN MI GA JU EMI MI LO- Jumokẹ Ọkọya-Thomas

Jumoke Okoya-Thomas

Aṣaaju awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, Ọnarebu Jumokẹ Ọkọya-Thomas ti sọ fun awọn agba ẹgbẹ naa pe ki wọn kilọ fun Oloye Kẹmi Nelson to jẹ olori awọn obinrin fẹgbẹ oṣelu ọhun nilẹ Yoruba.
O ni ki wọn kilọ fobinrin naa ko dẹkun lati maa kan oun labuku tabi yẹyẹ oun nita gbangba, nitoro ki i ṣe pe oun naa ko mọ nnkan to yẹ ki oun ṣe fun un.
O sọrọ yii ninu atẹjade to fi ranṣẹ sawọn oniroyin. O ni gbogbo abuku tobinrin naa fi n kan oun latigba toun ti depo aṣaaju awọn obinrin fun ẹgbẹ oṣelu APC lati inu oṣu karun-un ti to gẹ bayii.
 Ninu atẹjade naa lo ti so pe, ‘Eyi ni lati jẹ kawọn araalu mọ nipa iwa ainitiju ti Oloye Kẹmi Nelson n hu, to fi n ko abuku ba Ọnarebu Jumọkẹ Ọkọya-Thomas. Lọjọ Aje, Monde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ ni Kẹmi Nelson atawọn tọọgi mẹfa ja wọ ọfiisi alaga wa, iyẹn Ọnarebu Tunde Balogun nigba ta a wa ninu ipade oloye ẹgbẹ.
Kemi Nelson
O fi kun un pe nise ni ọkan lara awọn tọọgi obinrin naa, Ayọ Alli Balogun sọ foun loju awọn oloye ẹgbẹ yooku pe oun yoo foju oun ri mabo.
O ni, kaka koun fun un lesi, ṣe loun jade ninu ọfiisi alaga naa, ṣugbọn siyalẹnu oun, niṣe ni tọọgi naa lọ ba amugbalẹgbẹ oun, Alaaja Abiọdun to si doju ija kọ ọ debi pe wọn sare gbe obinrin naa lọ si ọsibitu nibi to ti lo gba itọju.
Jumọke Ọkọya-Thomas tun sọ ninu atẹjade naa pe gbogbo ọna loun gba lati fi nawọ ifẹ si Kẹmi Nelson ṣugbọn ti gbogbo rẹ ja si pabo
O ti wa rọ awọn agba ẹgbẹ naa pe ki wọn pe Kemi Nelson nibi ti wọn ti le ba a sọrọ, ki wọn si kilọ fun un pe ko jawọ ninu gbogbo iwa radarada ti obinrin naa hu ti ko yẹ ki won maa ba a nibẹ pẹlu ipo to wa. O ni, idaamu ti o n fun oun ti fẹ ga ju ẹmi oun lọ bayii, bee lo ti fẹ maa ṣakoba fawọn iṣẹ to wa niwaju oun.
Bakan naa lo fi kun un pe nnkan ti ẹgbẹ  oṣelu APC nilo lakooko yii ni isọkan lati le fi koju ibo to n bọ lọna. Bee lo tun gba awọn alatilẹyin ẹ niyanju lati gba alaafia laaye laarin ara won ki wọn si jọ maa wa bi ẹgbẹ naa yoo ṣe bori ninu ibo to n bọ lọna naa.


Post a Comment

0 Comments