GBAJUMO

GONGO SO LOJO TI OLUPAKO SHAARE FI LAHAOLA SALASHI JE AARE ADIMULA *GANI ADAMS ATAWON OBA ALAYE NI WON BA WON DE SHAARE

Aare Adimula tuntun, Alhaji Adesina

Ese ko gbero niluu Shaare nijoba ibile Ifelodun ni Kwara lana-an ojo Abameta (Satide) nigba ti Kabiesi ilu naa, Oba Abubakar Garba Dosunmu fi Dokita Yakub Adeshina Lahaola joye Aare Adimula akoko.
Bi awon lobaloba lati ipinle Kwara se wa nibe lojo naa, bee lawon oba nla-nla lawon ilu to jinna rere naa peju, ti Aare Onakakanfo, Iba Gani Adams paapaa ko gbeyin laarin awon omo Yoruba to wa ye Olupako ilu Shaare ati Lahaola Salashi si.
Okan lara awon omobibi ilu Shaare ni Dokita onisegun ibile yii, iyen Alhaji Lahaola Salashi n se. Okurnin ohun  lo ni ileewe awon olukoni akoko ninu ilu naa, iyen Adeshina College of Education. Bi ojumo ti mo ni ilu Shaare ti bere si gba alejo lorisirisi, bii omi ni won si n wo lo sinu ilu naa bi Olupako Shaare se n mura lati jawe oye le e lori.  
Ninu oro Aare Onakakanfo Gani Adams lojo naa lo ti sapejuwe igbese ti Olupako ilu Shaare gbe yii gege bi ohun iwuri nla ti yoo mu ilosiwaju nla ba ilu ohun, paapaa niru agbegbe ti won tedo si ati ile Yoruba lapapo.  O ni ayeye iwuye ohun ko sai tokasi ilosiwaju rere ati ibasepo gidi to n sele laarin awa Yoruba bayii.
Iba Gani Adams, Aare onakakanfo ile Yoruba
Bakan naa lo tun so pe asiko yii gan-an lo ye ki awon agbaagba ile Yoruba wa ilosiwaju rere fun asa ati isese wa, ati pe o se pataki fun won lati gbe igbese bi ojo ola Yoruba yoo se dara ju bayii lo laarin awon eya yooku ni Nigeria.
Siwaju si i, o ti wa ro Dokita Adeshina lati lo ipo e tuntun yii lati fi wa irepo ati ilosiwaju gidi laarin awon odo nile Yoruba. 
Ninu oro Olupo ti Ajase Ipo, Oba Sikiru Atanda Woleola Keji lo ti so pe eni ti oye ohun to si gan-an ni Olupako Shaare gbe e fun, ati pe okunrin naa yoo lo ipo ohun daadaa lati fi mu ilosiwaju gidi ba iran Yoruba ati Nigeria lapapo. O ni, Aare Adimula akoko niluu Shaare ko ni i ja awon eeyan e kule rara, nitori olooto eeyan to tun je akikanju gidi ni.
Olupako ilu Shaare, Alhaji Abubakar Garba Akande Dosunmu II ti sapejuwe ipo Aare Adimula yii gege bi oye nla ti Alhaji Yakub Adeshina Lahaola ti sise takuntakun fun niluu Shaare. O ni, “Oye to ye e ni, bee lo je ojulowo eeyan ti o to fise ogun ran lojo gbogbo.”


Post a Comment

0 Comments