![]() |
| Kayode Oshiriayo, Femi Kehinde, oludije labe asia egbe oselu AGA ati igbakeji e, Hafsat Lawal l'Osogbo |
Ese ko gbero ni gbongan nla
Afeni Event Centre nibi ti se olu ile egbe All Grassroot Alliance, egbe Eleyele
lasiko igba ti awon oloye egbe naa gbe asia le Onarebu Olufemi Lawrence Kehinde
lowo lati dije dupo gomina nipinle Osun.
Pitimu lawon ero pe, ti kaluku
si n darin lolokan-o-jokan lati fi idunnu won han si okunrin oloselu ti egbe
naa fa kale lati dije loruko e yii. Ni nnkan bi aago mewaa aaro lawon eeyan ti
n wo lo si olu ile egbe naa niluu Osogbo.
Kaakiri orile-ede yii si ni awon
omo egbe ohun ti yan eeyan wa lawon ipinle bii Eko, Anambra, Delta, Oyo, Ogun,
Ekiti, Ondo, Sokoto, Imo ati bee bee lo.
Ninu alaye ti Omooba Ayoade
Adanri, eni ti se alaga egbe ohun nipinle Osun se lasiko to gbe asia egbe naa
le alaga egbe ohun lapapo, Dokita Olukayode Oshiariyo lowo lo sapejuwe Olufemi
Kehinde gege bi oludije ti yoo mu itura ba ipinle Osun.
![]() |
| Pelu die lara awon omo egbe |
O ni, enikan ti Olorun fowo si
ni, o si da wa loju pe, ibo ti o n bo yii, egbe Eleyele ti se egbe wa ni yoo
jawe olubori ti a o si mu irorun ati ilosiwaju gidi ba awon eeyan Osun nile
loko ati leyin odi.
Dokita Olukayode Oshiariyo ni
tie dupe lowo awon eeyan ipinle Osun, paapaa awon omo egbe naa fun ife ti won
ni, o ni bo tile je pe egbe naa omo tuntun jojolo ni, sibe egbe mekunnu ti yoo
ko oriire nla ba araalu ni. O ni, “A ti n segbe lorisirisi lorile-ede yii lati
aye awon baba wa Awolowo, Azikwe, loooto ni won da egbe sile, ti won pe e ni ti
mekunnu, sugbon ta a ba wo o daadaa, egbe awon olowo ni, atawon ti won lenu
loro laarin ilu, sugbon egbe tiwa yii, egbe All Grassroot Alliance, egbe
Eleleye, egbe gbogbo-gboo ni, mekunnu lo ni in. Toro-kobo ni kaluku wa da ta a
fi gba iwe iforukosile egbe yii. Enikan soso bayii ko le fowo-soya wi pe oun loun
ni in, koda, enikan ko le so pe oun da owo to niye lori to egberun lona
ogorun-un naira (N100,000), toro-kobo ni kaluku da, bee owo ohun, a da a
kaakiri orile-ede yii ni. Ki i se egbe Yoruba, Ibo tabi Hausa nikan, ti gbogbo Nigeria
ni.”
![]() |
| Laafin Ataoja Osogbo pelu Kabiesi, awon Olori atawon omo egbe |
O fi kun un pe, egbe gbogbo
mekunnu Nigeria ni, to setan lati bu ororo itura si igbe aye awon eeyan wa. Ko
si ohun to n je baba isale ninu egbe wa, gbogbo omo egbe pata lo lenu, kaluku ni
ero won si se koko pelu.
Lojuese nibe naa lo ti bi awon omo egbe atawon
araalu wi pe se ki oun gbe asia egbe naa fun Femi Kehinde, ti won si hoo geee
wi pe ko gbe e fun. Bi gbajumo Amofin Femi Kehinde se gba asia egbe naa ree, ti
yoo si ba awon oludije yooku dupo ohun nipinle Osun losu to n bo.
Ninu oro oludije gan-an funra
e, okunrin omo Ile-Ogbo legbee Iwo nipinle Osun yii, to bere oselu lati odun 1987
gege bi Kanselo, to tun se oselu titi depo Asofin niluu Abuja dupe lowo awon
omo egbe atawon igbimo olusakoso egbe ohun fun igbagbo nla ti won ni ninu e.
Femi Kehinde ninu oro e so pe,
ohun to je egbe Eleye logun ati ijoba ti oun yoo se l’Osun ni bi igbe aye
irorun ati ilosiwaju gidi yoo se ba awon eeyan ohun.
O ni, “Ohun ibanuje nla lo je
bi a se n gbe ninu osi, bo tile je pe ori oro oniyebiye ni ipinle Osun ni
nikawo. Goolu to wa lawon agbegbe kan bii apa Ila-oorun Atakumosa ati Iwo-Ooorun
Atakumosa titi de aarin gbungbun Ife; bee lo wa ni Itagunmodi, Iperindo; Owu-Epe;
Ajana ko lonka. Awon goolu ti mo n so yii, ko sese digba ta a ba wale-wale ki a
too ri i, gbogbo jijin e ko ju bi ogorun-un mita (100m)lo, eyi to fun wa
lanfaani nla ju ti awon orile-ede bii South-Africa to je pe bii eedegbeta (500
meters) si isale ile lohun-un ni won a wa ki won too kan an goolu tiwon, bee ni
Ghana naa yoo gbe ile bii igba mita
(200m).
![]() |
| Oun lo fi idobale ki Ataoja Osogbo yii |
Femi Kehinde te siwaju pe, “Anfaani
nla ni awon ohun isura yii yoo ko ba wa, ati pe owo to le ni bilionu marun-un (5.2
b) lawon isura olowo iyebiye yii to. Egbe Eleyele setan lati wa ona abayo si
airise awon odo, anfaani wa lati dako repete lona ti igbalode, ti ounje a po
yanturu, awon osise atawon ti won ti feyinti yoo lanfaani si owo osu won. Ni
bayii, owo osu ti ijoba n je awon eeyan l’Osun ti di osu metadinlogoji (37),
ipinle Osun yii ni won ti n san owo osu aabo fawon osise ni gbogbo igba, gbogbo
eyi pata la maa mojuto ni akoko ogorun-un (100) ojo ti mo ba ti dori ipo.
“Gege bi iriri mi ninu ise
amofin fun odun marundinlogiji (35). A o fopin si inakuna, bi a o se so ipinle
Osun di ipinle to ni oro aje to po la o mojuto, ki igbe aye irorun le ba awon eeyan
wa. Ni kete ti a ba ti wole sipo gomina, owo osu won la o mojuto, bee ni gbogbo
gbese to wa nile pata la o wa ona lati yanju e. Ijoba tiwa ko wa lati ye idi
enikeni wo, bo tile je pe ko rorun lati depo ki eeyan ma se awon iwadii kookan,
sibe dereba to setan lati koju mo ibi to n lo fun ilosiwaju awon eeyan Osun ni
emi fe je, a n lepa enikan tabi dunkoko mo ijoba to se e koja ko si ninu
erongba temi, ise ilosiwaju yen gan-an ni pataki, ki aye awon eeyan ipinle Osun
le dara.”
Okunrin oloselu yii te siwaju
pe, ohun to se pataki ni bi a o se da ogo awon ileewe wa pada l’Osun, o je ohun
ibanuje bi ina eto eko se n jo ajoreyin l’Osun, awon omo wa ni won n se ipo to
lo seyin ju ninu idanwo ni Nigeria, o ti ni loju, o buru pupo ju.
O ni, ki eto ijoba yii le
kesejari la se mu igbakeji mi, Alhaja Hafsat Lawal, eni to ti feyinti gege bi
oluko-agba nileewe ni, bee lo tun je Musulumi ododo lati ilu Ila Orangun, ti emi
si wa lati Ile Ogbo nipinle Osun, bee ni mot un je Kristeni.
“Yato si eyi, a setan lati pada si bi a ti n se e tele,
eyele tiwa ko ni i ba onile je, ba onile mu tan, ko wa sa lojo isoro, gbogbo
oba alaaye pata nipinle Osun la o faaye gba, ti won yoo si ni aaye nla ninu ijoba
yii lati ba wa maa da si i. Awon oba ti awon oloselu asiko yii ko ka si gan-an
pelu ohun to n koba iselu Nigeria. Ipo nla ni ipo oba, bee la gbodo fun won
lowo tiwon.” Kehinde lo so o.
Ninu alaye lori bi egbe to je
tuntun yii nipinle Osun yoo se jawe olubori lo ti so pe, Oloye Olusegun Obasanjo
naa so o nigba kan to n degan Olusegun Mimiko wi pe inu igbo ni iroko n gbe, ta
lo mo egbe osleu Labour to sese de.
O ni, “Mimiko dije o si gba ipo
yen l’Ondo, bee lo sejoba fodun mejo, bakan naa lo sele l’Ekoo laarin Alagba
Michael Otedola to dije loruko egbe oselu NRC, eni ti ko ni baba isale, ti egbe
naa paapaa ko fese rinle daadaa to l’Ekoo, sugbon nigba to ti wa ninu akosile
Olorun, Otedola lo wole, to si sejoba daadaa. Bi oro egbe Eleyele se maa ri l’Osun
niyen, ijoba PDP ti su awon eeyan l’Osun, bee ni APC tawon Aregbesola naa, egbe
oselu AGA laye n fe bayii, awa si la o wole sile ijoba losu to n bo.”
Ti a ba wo ipinle Osun daadaa awon
ilu nla nla ta a ni nipinle yii fe to egberun meta (2,836) ti a ba mojuto ise
agbe daadaa, ipinle wa naa yoo ni anito-ati-aniseku. A setan lati da ileese ti
yoo maa ri si kata-kara awon ere oko sile (Market board). Ohun toju awon agbe
maa n ri ki won too ri awon ere oko won ta, leyin ti won ti se laala ki ere oko
le so, o je ohun to buru pupo. Fun idi eyi, a setan lati mojuto ise agbe daadaa,
a fe da ileese ti yoo maa seto bi won yoo se maa ri nnkan oko won ta daadaa, ti
eeyan ba ti mo wi pe ti oun ba sise yii, ibi ti oun yoo ta a si ti wa, ko si bi
ko se ni tera mo on, eyi gan-an lo maa n mu ilosiwaju ba eto oro aje ipinle.”
Lara ohun ti oludije dupo
gomina yii tun so pe o le mu idagbasoke ba oro aje ipinle Osun ni igbelaruge
awon ohun igbafe ati asa nipinle ohun. O ni, ti itoju to peye ati igbelaruge
gidi ba wa fun odun Osun Osogbo atawon ohun isenbaye mi-in ta a ni, ko si bi
ipinle wa ko se nii di ape-waa-wo-o, eyi ti yoo tubo mu ilosiwaju nla ba wa,
ise yoo po, ti ipinle Osun yoo si bo ninu ise ati osi.”
Ni kete ti won gbe asia egbe
ohun le lowo, toun naa ba awon omo egbe atawon araalu soro tan ni oun atawon
oloye ti gba aafin Ataoja Osogbo, Oba Jimoh Oyetunji Olanipekun lo. Nibe loun
atawon omo egbe e ti so erongba won lati dije dupo gomina nipinle naa, bee ni
won seleri fun kabiesi wi pe, bi itura yoo se ba mekunnu lo je egbe naa logun,
ati pe egbe mekunnu ponbele ni egbe AGA, egbe Eleyele n se.
Kabiesi ninu oro e dupe lowo
won, bee lo ro awon oloselu yii lati wa alaafia laarin ara won, ki won se sise
lori bi igbe aye irorun yoo se tubo ba Osun ati Nigeria lapapo.
Egbe oselu AGA ti ke si awon omo egbe naa lati bere ipolongo fawon eeyan ipinle Osun lati ojule de ojule fun igbaradi eto idibo ti yoo waye losu to n bo.
Lojo naa, bi awon omo egbe oselu AD se darapo mo won, bee lawon mi-in ninu egbe oselu APC ati PDP lati awon ijoba ibile orisirisi nipinle Osun naa wo wa sinu egbe oselu Eleyele.







0 Comments