Gomina Eko, Akinwunmi Ambode |
Egbe oselu PDP ti so pe oun
setan lati gba Ogbeni Akinwunmi Ambode lati dije dupo gomina leekan si i lodun
2019 ti egbe oselu APC ba fi le le e lodo won.
Tusde, ojo Isegun to koja loro
ohun bere were lasiko ti Ogbeni Babajide Sanwo-olu gba tikeeti egbe oselu APC
lati dije dupo gomina nipinle Eko. Latigba naa ni wahala ti wa, tawon eeyan si
ti n so pe, o see se ko soro fun Gomina Akinwunmi Ambode lati tun ri saa kan lo
si i lori ijokoo nipinle naa.
Jide Sanwo-olu |
Lojuese ti okunrin to ti sise
lawon eka lorisirisi nileese banki ati ninu ijoba ti fi ife e han lati dije ni
egbe kan ti oruko e n je Mandate Movement, ti won so pe o je ojulowo egbe to n
soju fun Asiwaju Bola Tinubu ti gbaruku ti i. Nibe yen gan-an lawon eeyan ti so
pe, saa keji Ambode, dajudaju, Asiwaju Bola Tinubu ko ni i ba a lowo si i.
Orisirisi awuyewuye lo ti gba
igboro kan lati nnkan bi ose kan seyin ti Jide Sanwo-olu ti so pe oun naa nifee
si ipo gomina ipinle Eko lodun 2019. Bawon kan se n so pe o see se ko je pe
wahala nla kan n lo laarin Ambode ati Bola Tinubu to fa a kale lodun 2015, bee
lawon mi-in n so pe o see se ko je pe okunrin oloselu naa ti se awon agbaagba
kan ninu egbe ni. Awon mi-in tie so pe, gbogbo ona tawon eeyan maa n gba je
mudunmudun nile ijoba lokunrin oloselu yii ko faaye e sile mo, sugbon to je pe
ise takuntakun tawon eeyan le ri laarin
ilu ni won lo koju mo. Won ni eyi gan-an lo mu awon oloselu kan ma fe ko tun
pada wa mo, nitori bi won se lero wi pe awon yoo ba ijoba e ko ni won ba a.
Ni gbongan nla City Hall l’Ekoo
lojo Aiku, Sannde to koja, pitimu lawon ero pe lati wa gbo nnkan ti Babajide
Sanwo-olu fe so fun won. Ki wa se awon eeyan lasan lo wa nibe, bi awon asofin
se wa, bee gege lawon asoju-sofin atawon ti won lenu daadaa ninu oselu ipinle
Eko, paapaa awon ti won je omoleyin Bola Tinubu.
Ambode ati Femi Otedola ti won loun naa fe dije |
Lara awon omo egbe oselu APC ti
won je asofin ati asoju-sofin niluu Abuja ti won wa nibe lojo naa ni Seneto
Gbenga Ashafa, Rotimi Agunsoye; ,Joseph Bamgbose; James Faleke; Jimi Benson,
Jide Akinloye. Bakan naa lawon agbaagba egbe bii Cardinal James Odunmbaku,
Demola Seriki; Dokita Tola Kasali, Omolola Essien; Oloye Kaoli Olusanya; bee gege lawon alaga
ijoba ibile idagbasoke metadinlogota (57) pata ti won wa l’Ekoo ni won peju
pese sibe lati satileyin fun Jide Sanwo-Olu.
Ninu oro e lasiko to n ba awon
eeyan soro lo so pe, oun setan lati seto ijoba ti kaluku yoo ti lenu oro
l’Ekoo, ati pe gbogbo awon ti won je agbaagba egbe ni won ko ni i maa kan
ilekun oun ki won too le ri oun ba soro nile ijoba.
Sanwo-Olu ti so pe bii oloselu
gan-an loun se fe sejoba toun l’Ekoo, ati pe gbogbo eto ti egbe oselu APC la
kale loun yoo tele, ti awon agbaagba egbe ko si ni i je agbele-he.
Sa o, bi wahala yii se de ba
gomina ipinle Eko lori bi yoo se pada si ile ijoba lodun 2019, egbe oselu PDP
ti so pe oun setan lati gba a wole, ti yoo si dije dupo ohun loruko asia egbe
awon.
Ogbeni Taofik Ganiyu, eni ti se
alukoro fun egbe naa l’Ekoo ti so pe, ti egbe oselu APC ba fi le Ambode kuro
ninu egbe, tabi ti won ba ko lati fun un lanfaani lati tun lo leekan si i, awon
yoo gba a wole. Bakan naa lo fi kun un pe irufe ise takuntakun ti okunrin naa
ti se nipinle Eko, anfaani nla ni yoo je fun egbe oselu PDP lati lo o, ti awon
yoo si jawe olubori.
O ni, a setan lati gba enikeni ti yoo ko
oriire ba egbe yii mora ki awa naa le jawe olubori l’Ekoo. Bakan naa lo tun so
pe oun ko ti i le fi gbogbo eni so o wi pe Femi Otedola, gbajugbaja onisowo ti
darapo mo egbe ohun abi o ti gba foomu lati dije. O ni, “Loooto lawon agbaagba
egbe wa n sise papo pelu awon alatileyin e lori igbese yen. Ti a ba ni iru Femi
Otedola naa ninu egbe wa gege bi oludije, aseyori nla lo maa je. Ohun to se
koko fun wa ni lati ni eni ti yoo mu alekun ba egbe wa.”
0 Comments