GBAJUMO

ÀRÒFỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌLÁDIÍPỌ̀ AJÍBÓYÈ... IKÚ TÚN ṢE NǸKAN

Ikú, o tún kan lẹ̀kùn nílé Ọbadọ̀fin!
Kí ló wá tún dé o?
Tóo fi ń wọlé wa ní lemọ́lemọ́
Ẹ̀ṣẹ̀ wo nìran Ọbadọ̀fin ṣẹ̀
Tóo fi fọ̀dẹ̀dẹ̀ wa ṣèyẹ̀wù?
N ò mọun tó yá ẹ̀gbọ́n mi lára gágá
Lọ́sàn-án gangan ọjọ́ọ Sátidé
Ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kejìlá ọdún tó kọjá
Tó dìde fù ú póòún ṣeré lòde
Kòńgẹ́ ló pàdé ikú lẹ́nu ọ̀nà!
Hùn, hùn hùn.
Ikú ò ṣe méní
Ikú ò kúkú ṣe méjì
Ikú ní kẹ́gbọ̀n-ọ̀n mi mọ́ọn ká lọ
Àkòjà, tí ń jẹ́ Dàda
Kí ló dé tóò bákú wọ̀yáàjà
Àkòjà, ìwọ kokú lọ́ná, o bẹ́ wọgbó
Àkòjà, mo ní ìwọ kokú lọ́nà, o bọ̀nà yà.
Kí ló dé tíkú fi pè ọ́ níjà tóo dojo
Kí ló dé tíkú fi pè ọ́ níjà tóo dọ̀dẹ̀ kalẹ̀
Òótọ́ ni péèyàn kì í lágbara lọ́jọ́ ẹ̀mí ò níí gbáyé
Òótọ́ ni pékú níí rọ gbogbo alágbára léegun
Sàgbàdàrìgí, ẹran ọlá wá jákùn léèkàn
Ọmọ Ifábíyìí, ó di gbéréé
A ké rara káyà ó já
Mákó Kuarà, Ọláńbíwọnnínú
Ó dìgbà-ó-ṣe
Eémọ́ọ̀sì Ọmọ Ẹ̀bẹ̀lókù
Ó dàrìnàkò
Ó wá dojú àlá réré
Àní, ó dọjọ́ àjínde ká tó tún ríra
Ọmọ Ẹlẹ́ẹ́kù oyè
Ọmọ Ọbadọ̀fin
Ìwọ lọmọ Òrùbúlòyè
Ìwọ la kọ̀ kàá káyà ó já
A da jìnnì jìnnì bọmọ ojó
O ti làjò àrèmabọ̀
Àmọ́ o
Mo dúpẹ́ o ò bá wọn kúkúùyà
Ọláńbíwọnnínú, ìwọ ò bá wọn kúkú ẹ̀sín
Ọkọọ Dúdú
Ọkọọ Pupa
Ọkọ Ayọọlá, mo ló digbéré
Ọkọ Fìlísíà, ó dìgbóse
Ọkọ Dúdúparíọlá
Ọmọ wọn lÁyédùn
Àkòjà oò
O ò sì rọ́jú dágbére fáya rere kóo tó pojú dé
Ọkọ Pupáyẹmí ọmọ wọn lÉgòsì ilé
O sì wá sáré rèwàlè àsà
Oò ṣoníwàtútù bí àdàbà ló dàbọ̀
Bàbá Adékúnlé wá fi wá sílẹ̀,
Kò gbóhun táyé n wí mọ́
Baba Olúwafẹ́mi, baba Tọ́ba
Ti sáré rọ̀run alákéji
Bàbá Olúwatóbi, bàbá Ṣẹ́gun ti rèwàlẹ̀ àsà
Ayọ̀kúnmi tíí Sọmọ ìkẹyìn wọn léńje léńje
Ń fomi ojú ṣèdárò lẹ́yìn akọni
Tẹbí, tará àtọ̀rẹ́ ń ṣelédè lẹ́yìn afínjú àdàbà.
Ohun tó ṣé mí ní kàyéfì, tó dûn mí jọjọ
Ni pé
Ikú ò jẹ́ o dágbere fẹ́bí, ará àtọ̀rẹ́
Kó tó pa ẹ́ lójú dé pátápátá
Háà ó mà ṣe!
Ìgbà tóo ṣíjú pẹ́ẹ́ níléè 'wòsàn
Lọ́jọ́ tó kọ̀la tóo dágbére fáráyé
Tóo rí mi pẹ̀lú ọ̀rẹ́ẹ̀ mi
Sámúsìnnì, ọmọ Ọlájídé
Ó jọun pé, o fẹ́ẹ́ dọ́gbọ́n dágbére fábúrò rẹ
Àbúrò tóo fẹ́ bí ẹyin ojú
Tóo ń pè níyọ̀ ìdílé yín
Àbúrò tóo ń gbàdúrà fún tọ̀sán tòru
Péyọ̀ rẹ̀ kò níí dòbu láéláé
Àbúrò tóò fẹ́ kéèrà ó rìn.
Bóyá
Ṣe lo sì fẹ́ẹ́ sọ̀rọ̀ kan pàtàkì fún “Púrọ́ọ̀fù”
Kóo tó rebi àwọn àgbà ń rè ni
Ṣùgbọ́n,
Ọ̀dájú ikú kọ̀, kò jóo lè wíun tóo fẹ́ẹ́ wí
Ìkà ikú kọ̀, kò jóo le sọ̀rọ̀ ìkẹyìn
Ẹ̀gbọ́n-ọ̀n mi òòò
Ọláńbíwọn’nú ò
Njẹ́ bóo délé, kóo kílé
Bóo dọ́nà, o bèèrè ọ̀nà
Àtètèdélé, iṣẹ́ẹ̀ mi làkọ́kọ́ jẹ́
Bá mi kí Iba wa, Ọbadọ̀fin
Kóo kí Iba Ifábíyìí Ẹlẹ́ẹ́kù oyè
Kóo kí Eléípó baba Bánkọ́lé
Jísẹ́ẹ̀ mi fún Iba Jèémíìsì Ajíbóyè
Jèémíìsì alàgbà, agbórí odó kọ̀wé ọmọge
Má gbàgbé Ìyáa Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́,
Kóo bá mi kí ìyá Adébọ́lá tulé ‘Ta l’Ẹ́kàn
Kóo tún jísẹ́ẹ̀ mi fún ìyáà Jókòó Ilẹ̀ẹ́gún
Má sàì bá mi kí 'Kọ́ládé bàbá Ọpẹ́
Tara ṣàṣà ṣe kúulé sí 'Láníyan Ọ̀dọbà.
Bá mi kí Làmídì Ojúróngbé
Kóo káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ Mojoyinọlá, Láwálé àtÒjòge
Má gbàgbé Dùnmọ́mi, Ajéèégbé atOyèéláràn
Kóo wá fúnraà rẹ ṣàlàyé fún ìyáa wa, Mọ́rìnóyè
Ohun tó fa sábàbí tóo fi kẹ̀yìn sáyé
Ìdí tóo fi kánjú tẹ̀le lọ sálákeji
Ó tọ́ kóo ṣàlàyè fún Ìyáa wa Mọ́rìnóyè.
Jẹ́ mi sáré kì ọ́ bí ànán se í kì ùnran rin ín
Ùwọ lọmọ ọlọ́bẹ̀ dídùn rìnsín rìnsín
Ọmọ ọlọ́bẹ̀ í sùkọkọ gbaingbanin létí ào
Ànán wí kọ́ọkọ tọ́ lá
Káàlè tọ́ ò
Ìn lọmọ aládé eó
Ọmọ arìnmìrinmi ìjòkùn
Ọmọ aléó lódù bí ìyere
Ọmọ alágogo àjílù gbanma gbanma níjọ́ ùnsinmi
Ọmọ Òrùbúlóyè
Ìnin lọmọ Ọ̀pabàbà mẹ́sin lẹ́sẹ̀
Ọmọ Awọ́sọwọ́yè yaàfin
Ọmọ alúlé lókè ọjà
Gẹ̀rẹ̀, Ọmọ adàgbá
É dùgbà
Ẹ̀gbán èmi òòòòò
Mìín wí kọ́ọ ma mà jọ̀kùn
Mìnín wí kọ́ọ ma mà jikòló
Gbogbo unun tini ìnyan ará uwájú bá í jẹ lajùlé ọ̀run
Naàn ni kọ́ọ bá an ẹ jẹ
Ìnyan ẹgbẹ́ àtọ̀rẹ́ í sùdárò lẹyìn rẹ.
Ẹgbẹ́ Ùdàgbàsokè Ùlálẹ̀
Ẹgbẹ́ Máítì
Àtẹgbẹ́ Ọmọlùgbẹ̀yìn ní sọ́ọ̀sì
Gbogbo rinan pátá le wí
Kọ́o sùnunre o
Ẹ́ mà dùgbà
Mì wí é dijọ́ àjíìnde kaa tó ríra
Sùnunre oooooooo
Ọmọ tẹ̀pọ́tán, Ẹ̀bẹ̀lékù, é dùgbà.

Post a Comment

0 Comments