GBAJUMO

ILEESE RADIO YINKA AYEFELE TI WON WO N’IBADAN *OKUNRIN NAA SO PE, ILE LASAN NI WON WO, FRESH FM SI N SISE DAADAA


Bo tile je pe nise lawon eeyan n sunkun, ti won n gbe ijoba ipinle Oyo sepe nla, sibe Yinka Ayefele to nileese Radio Fresh FM ti won wo danu ma ti soro, okunrin naa ti so pe, ki enikeni ma se sunkun mo, nitori ileese ohun si n te e siwaju. Ninu fonran kan to gba igboro kan bayii ti gbajumo olorin emi nni fi sigboro lo ti dupe lowo gbogbo awon eeyan to ba a kedun patapata, bakan naa lo dupe lowo ijoba ipinle Oyo, paapaa komisanna eto iroyin fun ipinle naa, Ogbeni Toye Arulogun.
O ma se o! lleese e ti won wo ree
Ayefele ninu oro e ti so pe okunrin naa gan-an lo pile wahala to deba ileese redio oun, ati pe nibi ti ijoba Oyo sin oun de yii, oun dupe gidigidi lowo won o, nitori pe oun ko mo rara pe oun le debe.
“Awa ko ba ijoba ja, bee la o bu won, ileese Redio wa paapaa ko tako ilana igbohun safefe, bi a se n soro yii, ileeese NBC to n ri si igbohun-safefe ti ran iko won wa lati ilu Abuja, emi si mo pe ese ko ni i deede se, o lohun ara ti Olorun tun fe se ni.” Yinka Ayefele lo so o.
Saaju asiko yii ni Yinka Ayefele ti ba awon oniroyin soro lori bi ijoba se loun fe wo ileese naa. Alaye ti okunrin yii se ni pe,”Ki i se ileese wa nikan lo wa ni egbe titi ni Challenge niluu Ibadan, bo se wa je pe oun nikan ni won fe wo yii, e je ki a maa wo o na.”
Toye Arulogun, okunrin
to so pe o pile idaamu oun ree
Siwaju si i, Ayefele ni, “Ohun ti ijoba Oyo n so ni pe a ko se tiwon, emi o mo ohun ti won fe lowo mi o, emi ki i se oloselu, bee latijo ti a ti soro nipa Abattoir, iyen ibi ti won ti n pa eran nipinle Oyo, ojo yen ni wahala wa ti bere pelu ijoba. Ileese Radio Fresh FM ti gbogbo aye ni, a ko le ma so oro to maa se ilu lanfaani tabi pe akiyesi ijoba sibi to ba ye. O ti le ni odun mewaa ti a ti ko ileese yen sibe, o se wa je asiko yii ni won bere si wa awawi lati wo o danu. Nibi ti oro ohun yoo yori si, e je ki a si maa wo o naa.”
Alaye ti Ayefele se fawon oniroyin niyen laipe yii ko too di pe ijoba ipinle Oyo wo ileese ohun mojumo oni Sannde, ojo kokandinlogun osu kejo odun 2018 yii.
Abiola Ajimobi, gomina won l'Oyoo
Okunrin yii si ti fidi e mule pe ile ti ileese Fresh FM wa ninu e nijoba wo danu, gbogbo eto ti ileese naa se si n te siwaju, bee lo ni ki awon eeyan ti won n seto sokan akin nitori ti oro ba ti ri bayii, nise loun maa n fa ohun gbogbo le Olorun lowo, ati pe o tun ni ohun ara oto ti Olorun fe fi isele naa se ninu aye oun ni.
Sa o, ileese ijoba ipinle Oyo paapaa ko ti i soro lori isele yii, gbogbo bi o ba se n lo la o maa je ki e gbo.

Post a Comment

0 Comments