GBAJUMO

ILEESE OKO OLOYUN GBETO ORO AJE WOLU, WITIWITI LAWON EEYAN N BO O

Alh.Fatai Yusuf Oko Oloyun

Lati le tubo mu igbe aye rorun fawon araalu, ileese OKO OLOYUN WORLD ti gbe eto nla kan kale, nibi tawon eeyan yoo ti lanfaani lati maa fowo won sowo pelu ileese naa, ti ere goboi yoo si maa wole sapo won, lai ni i kuro ni koro yara won.
Ohun ti awon alase ileese yii so ni pe, anfaani ti wa lati ba won dowopo, ti eeyan yoo si maa je ere ida mewaa (10%) losoosu lori iyekiye ti eeyan ba gbe kale lati ba won fi sowo.
Ninu oro Alhaji Fatai Yusuf to nileese OKO OLOYUN lo ti so pe, "A gbe eto ohun kale fun anfaani araalu ni. Owo ti eeyan le fi ba wa dowopo bere lati egberun lona ogorun-un naira (N100,000), orisirisi oja wa ni won yoo maa fi owo yii ra, awon ti won maa ta a ti wa nile, bee leeyan to ko owo yii kale yoo kan wa ni koro iyara re, ti yoo maa gba ida mewaa losoosu. Lojo to ba si so pe oun ko se mo, oun fe gbowo oun, anfaani wa lati gba iye to ko lori oja wa pada. Bee la tun n gbe kiosk wa, iyen apoti itaja ileese Oko Oloyun kale fun awon araalu lofee. Gbogbo aye lo mo wa gege bi olooto, awa kii  sa pamo je eeyan niya, irorun araalu lo je wa logun."
Alaye bi won se gbe eto ohun kale ree;
Ø Eni to ba gbe owo egberun lona ogorun-un naira (N100,000) kale, yoo lanfaani lati maa gba owo egberun mewaa naira (N10,000) losoosu.
Ø Eni to ba gbe owo egberun lona eedegbeta naira (N500,000) kale, yoo lanfaani lati maa gba owo egberun lona aadota naira (N50,000) losoosu.
Ø Eni to ba gbe owo milionu kan naira (N1million) kale, yoo lanfaani lati maa gba owo egberun lona ogorun-un naira (N100,000) losoosu.
Ø Eni to ba gbe owo milionu marun-un naira (N5milionu) kale, yoo lanfaani lati maa gba owo idaji milionu kan naira (N500,000) losoosu. 
Ø Eni to ba gbe owo milionu mewaa naira (N10 milionu) kale, yoo lanfaani lati maa gba owo milionu kan naira (N1milionu) losoosu.
Bi eeyan ba se gbe owo sile si i, bee gan-an ni ere re yoo se po to, ida mewaa owo ti eeyan ba ba won fi dowopo ni eeyan yoo maa
gba losoosu.
Won ti fidi e mule wi pe, aaye ti si sile fawon eeyan lati kan si ileese won to wa ni Oko Oloyun Health Palace ni Oko Oloyun avenue, ni Hotel Bus-stop ni Igando l’Ekoo fun ekunrere alaye.
Lara awon egboogi ara to n sise bii idan to n jade lati ileese naa niwonyi; FIJK; WIPER; PAKURUMO; HERO; MEGATO ati bee bee lo. 

Post a Comment

0 Comments