Gbogbo eto lo ti pari lori ayeye
isinku Alhaja Shakeerat Modupeola Ogunremi, eyi ti yoo waye laipe yii niluu Eko.
Ninu atejade ti okan lara awon
omo oloogbe ohun fi sowo si wa, iyen Alhaji Olatunji Azeez Ogunremi, eni tawon
eeyan tun mo si Jejeti lo ti so pe, “A dupe lowo Olorun fun igbe aye rere ti
mama wa lo, idi niyi ti a fe fi f’emi imoore han nipa sise ayeye oku naa lona
to yato, a fe ko ebi jo, bee la fe pe awon ara paapaa, lati wa ba wa se eye
ikeyin fun iya wa, mama rere to lo gbogbo ohun to ni pata fun oju ona Olorun. Ise
rere ti won se laye, awa omo ti setan lati te siwaju ninu e, ninu eyi ti oruko
won ko ni i pare laelae.”
Ninu oro Alhaji Akeem Idowu Ogunremi,
eni tawon eeyan tun mo si Olomitutu ni tie lo ti so pe, “Ojulowo iya ni, bee
abiyamo gidi ni won paapaa, ti ki i boju weyin lati mu aye rorun fun
ateru-atomo.”
Olomitutu ti fi kun oro e pe, “Gbajumo
olorin fuji nni, Alhaji Wasiu Ayinde Marshal ni yoo forin da won alejo wa
laraya, bee ni Ifankaleluya ati Alhaji Dan Wahab ni won yoo jo dari eto pelu awon awada lolokan-o-jokan.”
Sannde ojo ketalelogun osu
kejila odun (23rd of December, 2018) yii gan-an ni won so pe ayeye ohun yoo
waye ni gbagede Police College, Oba Akinjobi way, nidojuko tesan olopaa Area F,
n’Ikeja, l’Ekoo.
Odun 1945 ni won bi Alhaja
Shakeerat Modupeola Ogunremi, to si jade laye lodun 2018, eyi to fi han wi pe
mama naa lo odun metalelaadorin laye. Opo omo atawon omo omo lo gbeyin oloogbe
yii.
0 Comments