Lati fopin si idaamu
ti Minisita fun eto isuna owo, Arabinrin Kemi Adeosun n koju latari ayederu iwe
eri isinjoba ti won so pe obinrin naa n lo, ni bayii o ti salaye lekunrere bo
se ko sowo awon onijibiti ti won ko o sinu wahala ohun.
Ninu leta ikowe-fise-sile
to fi sowo si Aare Muhammed Buhari lo ti salaye lekunrere bi oro ohun se ba oun
lokan je gidigidi.
Ninu leta ohun lo ti
salaye pe ilu London ni won bi oun si, ti oun si ka gbogbo iwe oun nibe ki oun
too wa si Nigeria lasiko ti oun pe eni odun merinlelogbon.
Kemi Adeosun fi kun
oro e pe, “Saaju ki n too wa si Nigeria, eekookan ti mo maa n wale, a maa n wa
se olide ni, gbogbo igba ewe mi pata, ilu oyinbo ni mo ti lo o. Nigba ti mo si
pada si orile-ede yii, mo ti wa leni odun merinlelogbon. Asiko yen gan an ni
oro isinjoba waye. Lojuese naa lawon eeyan ti so pe, mo ti koja eni ogbon odun,
fun idi eyi, mi o letoo lati sinjoba mo, sugbon anfaani wa fun mi lati gba iwe
eri, eyi ti yoo safihan wi pe, mo ti koja ojo ori to ye ko se e ni mi o se ba
won kopa.”
Obinrin to ti lo odun
meta o le ninu ijoba Muhammed Buhari yii fi kun un pe, oun ko mo pe awon eeyan
ti oun gbe ise naa fun lati ba oun gba iwe eri, ayederu ni won se fun oun. O
ni, “Mi o de inu ogba NYSC ri, bee ni mi o mo bi won se n se nibe. Awon eeyan
ti mo fokan tan ni won gbe ayederu le mi lowo.
“Mi o sese maa lo iwe
eri ohun nipinle Ogun, ti ko si si wahala kankan ki awuyewuye yii too bere.
Gege bi enikan to korira iwa ibaje, eyi gan-an lo mu mi kowe fipo mi sile lojo
Eti, Fraide, ojo kerinla osu kesan-an kuro ninu ijoba Muhammed
Buhari. Mo dupe lowo Aare fun anfaani nla ti won fun mi, bee ni mo dupe lowo
gbogbo awon ta a jijo sise pelu, mo nigbagbo wi pe, ojo ola orile-ede yii yoo
dara, nitori ise takuntakun ni Aare Muhammed Buhari n se.”
0 Comments