GBAJUMO

LAMIDI ADAMS, ENI TI SE BABA AARE ONAKAKANFO TI KU O

Iba Gani Adams
Kaakiri agbaye ni won ti n ranse ibanikedun tawon mi-in paapaa n wo wa ki Iba Gani Adams, eni ti se Aare Onakakanfo ile Yoruba latari iku to pa baba to bi i lomo.
Satide, ojo Abameta to koja yii ni Alagba Lamidi Adams, eni to bi Aare Onakakanfo ile Yoruba jade laye leni ogorin odun (80).
Osibitu aladaani kan niluu Eko ni baba naa ti mi eemi ikeyin lowo aaro ojo Abameta ohun.
Ninu oro ti Aare Onakakanfo fi sita, Iba Gani Adams lo ti salaye pe bi eto isinku oloogbe ohun yoo se waye yoo maa bo setiigbo gbogbo araye laipe yii.
Ileese kan ti won n pe ni Desmomy Nigeria Ltd, ileese awon oyinbo ara Italy kan ni baba naa ti sise daadaa, nibi to ti je oludari eka to n mojuto oro oko ati irinna e. Leyin to kuro nibe lo da ileese tie naa sile, nibi to ti n fi moto akero sowo.
Lara awon to gbeyin Oloogbe Lamidi Adams ni Iba Gani Adams ati opolopo omo atawon omo omo.  

Post a Comment

0 Comments