“Ki oye esin Islam tubo le ye
awon eeyan kaakiri agbaye, paapaa lati fidi e mule iha ti Olorun oba ko si esin
yii, eyi gan-an lo mu mi gbe rekoodu Allahu Ni jade, ti mo si tun gbe e sori
ero ayelukara, iyen youtube.”
Lasiko ti gbajumo olori esin
Islam, Alhaja Rodiat Sanni Adeboye to fi ilu Dublin ni orile-ede Ireland sebugbe
ba Magasinni yii soro lo fidi oro ohun mule.
Rodiyat, eni tawon eeyan tun mo
si Hello Olorun te siwaju ninu oro e wi pe, “Esin to pe ti ko ni abawon kankan ni
Olorun fun awa Muslumi. Ati pe, Al’qur’an ti Olorun se ni iwe aponle ti a fi n josin
ohun ti lohun gbogbo pata ninu fun eni to ba setan lati tele Anobi ojise ati
Olorun oba alaaye to da wa. Pataki esin Islam ati iha ti Olorun ko si i lohun
ti a se orinkinwin alaye e sinu rekoodu tuntun yen. Bee ohun to mu wa gbe e sori
ikanni ayelukara, iyen youtube ni pe, kaakiri agbaye lawon eeyan yoo ti lanfaani
lati wo o, ti won yoo si tubo gbo ihinrere nipa Olorun ti a saponle e sinu e.”
Alhaja Rodiyat Sanni Adeboye je
okan lara awon omo orile-ede yii to n gbe niluu Dublin, Noosi, iyen olutoju
awon alaisan ni paapaa, ki too fi ebun nla, iyen orin kiko ti Olorun jogun fun
un fi maa se waasu nipa Olorun, Anobi Muhammed ati esin Islam ti ojise nla wa
kede e faraye.
Lara awon rekoodu to ti gbe
jade ni Hello Olohun, Islamic News, I love Muhammad ati Allahu ni to wa nita
bayii, eyi to ti wa lori youtube pelu.
E le wo fido ALLAHU NI loju
opopo yii:
0 Comments